#omooodua
Explore tagged Tumblr posts
Text
Gbọ́ ń táwọn èèkàn ìlú ṣọ lẹ́yìn Búrùjí Kashamu
Gbọ́ ń táwọn èèkàn ìlú ṣọ lẹ́yìn Búrùjí Kashamu Bí ọmọ èèyàn bá wá sílé ayé, ìgbàgbọ́ Yorùbá ní pérúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ wáyé wá nájà ni. Ènìyàn ò sáà lè tajà tán kò sùn sínú ọjà, àti pé n tí kóówá gbe wá sínú ayé fún títà kò papọ̀. Ìbà Ọ̀jẹ́túndé Asòlẹ̀kẹ̀ Olorì alágbàáà àná tó sílẹ̀ bora. Ó ní èèyàn tó wáyé wá ta góòlù kò papọ̀ mọ́ tẹni wáyé wá ta ẹ̀kọ.Ẹni o wá tẹ̀kọ ṣe é ṣe kó tètè sẹ́rí wálé, góòlù kò yá títà bí ẹ̀kọ.Gbogbo àsamọ̀ yìí ló díá fún pé n tá a bá wá tá láyé ní yóó ṣọ bí ìrìnàjò yóó ṣe pẹ́ tó tàbí yá sí. Kò sí nínú ìròyìn mọ̀ pé Kofi -19 ń soro bí agbọ́n láàrin àwọn èèkàn ọmọ bíbí Orílẹ̀ yìí tó lóókọ lóókì, ọ̀kan pàtàkì sí ní Buruji Kashamu ẹni tí a fi àkójọpọ̀ ìwòye àwọn èèyàn lẹ́yìn rẹ̀ sọ di ìròyìn. Ṣé lọ́jọ́ a kú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè. Gbólóhùn yìí ló bi Onírúurú gbólóhùn tó ń fọhùn lẹ́yìn ikú èèkàn olóṣèlú n nì,Buruji Kashamu.Ṣé gángan láyé pẹ̀lú ojú méjì, ìbí tó bá sì gbà kójú sí kóówá ní yóó ṣọ bí ìròrí rẹ̀ yóó ṣe lọ. Bí àwọn ìlúmọ̀ọ́ká àti olókoòwò ṣe n dárò àgbà ọ̀jẹ̀ olóṣèlú náà ló fẹ́ ẹ̀ jẹ́ àrà ọ̀tọ̀.Díẹ̀ lára àwọn tó ṣọ tinú wọn ni Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ Ẹbọra Owu.Bàbá náà ṣọ̀rọ̀ ìkẹ́dùn pé olóògbé náà kú . Bẹ́ẹ̀ ló bó o lójú pé Buruji khasamu rí gbogbo àǹfààní òfin lò láti borí àwọn Onírúurú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án nílẹ̀ yìí àti lókè okùn síbẹ̀ ikú ti wá mú un lọ. Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Dàpọ̀ Abíọ́dún ti sàpèjúwe Sẹ́nétọ̀ Búrùjí Kashamu gẹ́gẹ́ bí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ọmọnìyàn. Read the full article
0 notes
Photo
Baba ni Baba n je lojokojo!! A toast to the Boss of Bosses! The Dexterous Don of Filmmaking! The Father of Ingenious Yoruba Cinema of the 21st century. Happy birthday, Alagba @tkelani #Happybirthday #Filmmaker #AfricanMovies #veteran #AfricanCinema #africanfilmmakers #AwardWinningDirector #Translator #OmoOodua #Yorubaculture #Peodavies #MyPRLife #PRlifestyle #prconsultantlagos #promoterofgoodworks #trustedadviser https://www.instagram.com/p/BuV4BkOhNVY/?utm_source=ig_tumblr_share&igshid=g7zn9lo5dqkt
#happybirthday#filmmaker#africanmovies#veteran#africancinema#africanfilmmakers#awardwinningdirector#translator#omooodua#yorubaculture#peodavies#myprlife#prlifestyle#prconsultantlagos#promoterofgoodworks#trustedadviser
0 notes
Text
Fìdáù Ajímọ̀bi, ẹbí nìkan ní wọ́n ń retí–Ẹbí Ajímọ̀bi
Fìdáù Ajímọ̀bi, ẹbí nìkan ní wọ́n ń retí–Ẹbí Ajímọ̀bi Ṣé wọ́n ní kìí jẹ́ ti baba t’ọmọ, kó mọ́ ní ààlà. Èyí ló díá fún bí àwọn ẹbí olóògbé Abíọ́lá Ajímọ̀bi tí sàlàyé pé ,kí àwọn olùkẹ́dùn, ó má wulẹ̀ dààmu yọjú sí bi fìdáù, ní ìbámu pẹ̀lú n tí àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì n sọ , bí ó ti jẹ́ pé òní, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Keje, ni àdúrà ọjọ́ kẹjọ yóó wáyé fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀rí tó di olóògbé, Sẹ́nétọ̀ Isiaka Abíọ́lá Ajímọ̀bi. Ètò àdúrà náà, Fìdáù, wà ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àti ìṣẹ ẹ̀sìn Islam. Ìdílé olóògbé sọ nínú Ìkéde tó fi síta fún ètò àdúrà náà pé, ẹbí Ajímọ̀bi nìkan ni ètò àdúrà náà wà fún, nítorí òfin tó rọ̀ mọ́ ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì. Ṣùgbọ́n ṣá, wọ́n ní àwọn aráàlú yóó ní àǹfààní láti wo bí ètò àdúrà náà bá ṣe ń lọ lórí amóhùnmáwòrán àti lórí ẹ̀rọ ayélujára. Ọjọ́ kẹẹdọgbọn, oṣù Kẹfà, ọdún 2020, ni Abíọ́lá Ajímọ̀bi kú, síléèwòsàn First Cardiologist, tó wà nílùú Èkó, lẹ́yìn tó ní àrùn Kofi-19. Ẹni àádọ́rin ọdún olóògbé Abíọ́lá Ajímọ̀bi ko tó tẹ́rí gbaṣọ. Fẹ́mi Akínṣọlá Read the full article
0 notes
Text
Colourful Photos: The Olowo of Owo Kingdom
His Imperial Majesty, Alaiyeluwa Oba Ajibade Gbadegesin Ogunoye III, The Olowo of Owo and Paramount Ruler of Owo KingdomPicture: Igogo festival 2019 See more photos bellow Read the full article
0 notes
Text
O̩jó̩ ìdìbò kò sún síwájú ní Edo – INEC
O̩jó̩ ìdìbò kò sún síwájú ní Edo – INEC Alaga patapata fun eto idibo ni orileede yii, Ojogbon Mahmood Yakubu lo n salaye yii ni ilu Abuja.O ni pelu rogbodiyan to n lo ni ipinle Edo, awon kan ti n gbee poori enu pe INEC maa fi kun ojo idibo. O ni ko si ohun to joo. Yakubu ni ojo kokanla osu kesan-an odun yii ni idibo si ipo gomina maa waye ni ipinle naa. Alaga yii ni gbogbo fifi oruko sowo si ajo INEC naa wa laarin ojo mewaa si asiko yii. O ni o pe ju,aago mefa irole ojo kokandinlogbon osu kefa yii ni iforuko sile naa maa dopin. Yakubu ro awon egbe oselu meedogun to maa dije du ipo gomina maa ki won tele ofin orileede yii ati ti alaale oselu. Alaga nii ki won ma se gbagbe nnkan merin to se pataki ki won to foruko asoju nibi idibo abele ranse si ajo oun. O ni oloselu to fe dije du ipo gomina gbodo je omo orileede yii, o gbodo pe omo odun marundinlogoji o kere tan, o gbodo je omo egbe oselu naa, bee si ni eni naa gbodo kawe, o kere tan iwe mewaa. Mahmood Yakubu nu leyin gbogbo eyi,idibo lo ku ni ojo idibo. Yínká Àlàbí Read the full article
0 notes
Text
Ilé ẹjọ́ kòtẹ́mílọ́rùn yọ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC Adams Oshiomhole nípò
Ilé ẹjọ́ kòtẹ́mílọ́rùn yọ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC Adams Oshiomhole nípò– Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti ilú Àbújá ti yẹ àga mọ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Adams Oshiomhole nídìí Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́tà ti adájọ́ Eunice Onyemanam sójú fún ni wọ́n fẹnu kò láti jan idájọ́ tí ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ dá tẹ́lẹ̀ lóntẹ̀ Sáájú ni Oshiomhole ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ tí àdájọ Abubakar Yahaya sì dájọ pé kí ìdájọ́ náà dúró náà kí ó ṣì máa ṣe alága lọ́ títí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yóò ṣe fìdímúlẹ̀. Adájọ́ Onyemanam tó dárí ẹjọ́ tó wáyé l’ọ́jọ́ ìṣègùn ló dá ẹjọ́ náà ló fídí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kékeré tó yọ Adams Oshiohmole gẹ́gẹ́ bí alágá nínú ọṣù kẹta ọdún yìí ṣe nǹkan tó yẹ àti pé, ẹjọ́ kòtẹ́mílọ́rùn tí Oshiomhole pè kò fìdì múlẹ̀. Fẹ́mi Akínṣọlá Read the full article
0 notes
Text
Ebo - The weapon of all true traditionalist.
Ebo is powerful Ebo is prayer Ebo solves the unseen problems Ebo helps prevent tribulations Ebo cleanse my soul It makes me feel complete Ebo doesn't require human part Ebo is pure Ebo is the key I have used Àkùko to offer Ebo for victory I have used Etù to offer Ebo for peace of mind I have used Eyelé to offer Ebo for wealth I have used Abo adìye to offer Ebo for good spouse I have used Eku and Eja to offer Ebo for good children May all our Ebo be accepted by Olodumare Agotun. Ase!!! " ~Owomide Read the full article
0 notes
Text
Ọ̀ọni ilé ifẹ̀ bẹ̀rẹ̀ fínfín ìtagbangba ní Ifẹ̀
Ọọ̀nirìṣà ilé Ifẹ, jìngbìnì bí àtẹ àkún,Ọba Adéyẹyè Ẹnitan Ogunwusi bẹ̀rẹ̀ fínfín àwọn ìta gbangba gbogbo ní ìlú Ilé Ifẹ̀ lẹ́yìn tó kéde ríra àwọn ohun èlò afínko láti dẹ́kun ọwọ́jà àrùn apinni léèmí COVID-19. Ọba Adéyẹyè ra àwọn irinṣẹ́ afínko tí wọ́n ṣe lábẹ́lẹ́ tí owó rẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́jọ náírà láti ṣe ìrànwọ́ fún ìgbésẹ̀ Ìjọba lórí wíwa wọ́ àrùn apinni léèmí Coronavirus bọlẹ̀. Kábíyèysí Ọọ̀nirìṣà kò ṣàì tẹnumọ́ pàtàkì fínfín àwọn ìta gbangba gbogbo káàkiri ìlú, ìpínlẹ̀ àti jákèjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Read the full article
0 notes
Text
Àfàìmọ̀ Kí Coronavirus Má Dà Bí I Ti China Tabi Italy- Mínísítà Kìlọ̀
Ẹni mẹ́rin mì ìn kó àrùn apinni ní mímí èèmii coronavirus ní Nàìjíríà,àfàmọ̀ kò mọ́ dà bí i ti China,l Italy— Mínísítà kìlọ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ìgbọrọ̀ sàn ju ẹbọ rúrú fún ẹni tó bá fẹ́ gbọ́ ni o. Ó ti di ogójì èèyàn tó ti lùgbàdì àrùn coronavirus báyìí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lẹ́yìn tí àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn ní Nàìjíríà, NCDC kéde àwọn mẹ́rin míì tó ti ní àìsàn náà lálẹ́ ọjọ́ Ajé. Àjọ NCDC ṣàlàyé pé mẹ́ta nínú àwọn èèyàn wá láti ìpínlẹ̀ Èkó nígbà tí ẹyọ kàn tó kù wá láti olú ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Abuja. NCDC ní àwọn méjì nínú wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ rìnrìn àjò dé láti òkè òkun ni. Gẹ́gẹ́ bí àlàyé àjọ NCDC lójú òpó Twitter rẹ̀, èèyàn méjì nínú àwọn ogójì èèyàn tó lùgbàdì àrùn Covid-19 ní Nàìjíríà ti kúrò nílé ìwòsàn. Èèyàn kan ti dèrò ọ̀run nínú àwọn tó lárùn náà ní Nàìjíríà, ọjọ́ Ajé ni ọkùnrin náà ẹni ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rin kú. Ohun tí a gbọ́ ni pé ọkùnrin ti ní àrùn ìtọ̀ ṣúgà àti àrùn jẹjẹrẹ lára tẹ́lẹ̀ kí ó tó lùgbàdì coronavirus. Ní báyìí, èèyàn méjìdínlọ́gọbọ̀n ló wá láti ìpínlẹ̀ Èkó nínú ogójì tó lárùn náà ní Nàìjíríà, méje Èèyàn méjì wá láti ìpínlẹ̀ Ogun, nígbà tí ìpínlẹ̀ Èkìtì, Oyo àti Edo ni ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀wẹ̀, mínísítà fún ètò ìlera, Dókítà Osagie Ehanire ti sọ pé àfàìmọ̀ kí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà náà ó má dàbí ti orílẹ̀-èdè China àti Italy lórí bí ọ̀rọ̀ coronavirus ṣe ń lọ yìí. Mínísítà ní ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà tó ní àrùn coronavirus ni wọ́n ń déjú mọ́lé, dípò kí wọ́n jáde fún ìtọ́jú kí àrùn náà má ba à ran àwọn mìíràn. http://iroyinowuro.com.ng/2020/03/24/afaimo-ki-coronavirus-ma-da-bi-i-ti-china-tabi-italy-minisita-kilo/ Read the full article
0 notes
Text
Fayemi, ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) kìí ṣe Kano tí wọn ti ń yọ Emir lórí oyè… Alaafin
Àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí ojú òpó ìkànsíraẹni Twitter ti dásí ọ̀rọ̀ láàrin Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ekiti, Kayode Fayemi àti àwọn ọba ní ìpínlẹ̀ náà. Èyí kò sẹ́yìn lẹ́tà tó jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára níbi tí Aláàfin Ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta ti kìlọ̀ fún gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti láti ṣọ́ra ṣe, ki o si tẹlẹ jẹjẹ. Ìròyìn ohun jáde pé, Gómìnà Fayemi ni wọ́n ló fi ìwé wítẹnuùrẹ ránṣẹ́ sí àwọn ọba mérìndínlógún ní ìpínlẹ̀ nítorí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí òun lẹ́nu. Fayẹmi ni wọ́n ló sọ pé àwọn ọba náà kọ̀ láti wá si ìpàdé àwọn lọ́balọ́ba àti Ìjọba láti Oṣù Kẹjọ, ọdún 2019 nítorí náà, kí wọ́n sọ ìdí tí wọ́n fi gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ Aláàfin nínú lẹ́tà tí wọ́n ló kọ sí Fayẹmi sọ wí pé, àgbáríjọpọ̀ àwọn ọba ní ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) ló fọwọ́sowọ́pọ̀ fi ìkìlọ̀ náà ránṣẹ́ sí gómìnà náà, láti máṣe fi orí adé tẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ rẹ̀. Aláàfin ní inú àwọn ọba náà kò dùn nítorí pé Gómìnà Fayemi fi ọba tó kéré ní ipò jẹ adarí ẹgbẹ́ àwọn lọ́balọ́ba nípìńlẹ̀ náà, Ìdí sì nìyí tí wọ́n ṣe gbé ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé. Àmọ́ àwọn ènìyàn to fèsì lórí Twitter sí lẹta náà sọ wí pé, ohun tí Aláàfin ń sọ yìí ló ń kìlọ̀ fún Fayemi wí pé, ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) kìí ṣẹ̀ ìpínlẹ̀ Kano tí gómìnà ti ń yọ Emir, tí yóó sì le kúrò ní ìlú nígbà tó bá wù ú. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn míràn sọ wí pé, ìbẹ̀rù bojo mú àwọn ará Èkìtì nítorí Fayemi fẹ́ yọ Èwí ti ìlú Ado-Ekiti, Oba Rufus Adejugbe àti àwọn ọba mọ́kànlá míràn, tó ń fapá jánú sí gómìnà ìpínlẹ̀ náà. Fẹ́mi Akínṣọlá Read the full article
0 notes
Text
Pa Kasumu, ó dìgbà kan ná
Kayode Odumosu,papòdà lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rin Gbajúgbajà òṣèré tíátà Kayode Odumosu tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Pa Kasumu ti juwọ́ ìgbẹyìn sáyé pé ó dìgbàkan. ”Èèyàn dáadáa ni wọ́n yàtọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ òṣèré tíátà.Ikú wọ́n jẹ́ eléyìí tó fi ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lẹ́mìí” Yàtọ sí Mr Latin àwọn òṣèré míràn bí Foluke Daramola ti fi ìkéde ikú Pa Kasumu sí ojú òpó wọn ní Instagram pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìkẹ́dùn ikú rẹ̀. Ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Kẹta ọdún 1953 ni wọ́n bí Kayode Odumosu ní ìlú Ìbàdàn. Ọmọ Odogbolu ní ìpínlẹ̀ Ogun ni a gbọ́ pé Bàbá rẹ̀ jẹ́ tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ Abeokuta. Ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀ eré sinimá tí àwọn èèyàn sì mọ́ ọ̀ gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtarìgì nínú awọn adẹrinposonu eré tíátà lédè e Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́ṣì. Lọ́jọ́ Àìkú ní Ààrẹ àwọn òṣèré tíátà Yorùbá ní Nàìjíríà Bolaji Amusan Mr Latin fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn. Ó ti tó ọjọ́ mẹ́ta tí àìsàn ti ń bá Pa Kasunmu fínra,k kí ó tó wá já sí t’ọlọ́jọ́. http://iroyinowuro.com.ng/2020/03/02/pa-kasumu-o-digba-kan-na/ Read the full article
0 notes
Text
Òòlù ìdájọ́ ré bá Fúnkẹ́ Akíndélé àti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn, owó ìtánràn, ìgbélé tipátipá, iṣẹ́ ìsìnlú bíi bọ̀kílẹ̀ àfojúdi .
Kò sí n tó burú kí abẹ òfin ba Ògbó Awo tó bá ń se bí ọ̀gbẹ̀rì . Ilé ẹjọ́ ti dá gbajúgbajà òṣèré sinimá, Fúnkẹ́ Akíndélé àti ọkọ rẹ̀ Abdulrasheed Bello lẹ́jọ́ pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó lòdì sí òfin kónílégbélé tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó gbé kalẹ̀ lórí dídẹ́kun àjàkálẹ̀ àrùn Coronavirus nípìńlẹ̀ Èkó àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ilé ẹjọ́ rán àwọn méjéèjì lọ sí iṣẹ́ ìsìnlú fún wákàtí mẹ́ta lóòjọ́ fún ọjọ́ mẹ́rìnlà, yàtọ sí ọjọ́ Sátidé àti Àìkú. Bákan náà ni iléẹjọ́ ní kí wọ́n san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn náírà. Bákan náà ni ìdájọ́ ọ̀hún tún ní kí ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́kọláyà náà yóó lọ sí ibùdó pàtàkì mẹ́wàá ní ìpínlẹ̀ Èkó láti ṣe ìdánilẹ́kọ́ọ̀ àti ìlanilọ́yẹ lórí ìjìyà tó wà fún ẹni tó bá ṣoríkunkun sí òfin kónílé ó gbélé. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbọdọ̀ fi orúkọ àti nọńbà ìbánisọ̀rọ̀ gbogbo àwọn tó kópa níbi àjọyọ̀ náà. Bákan náà nìròyìn míì ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, Azeez Fashola tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Naira Marley tí àwọn agbófinró tí kọ́kọ́ kéde ṣaájú pé àwọn ń wá ló tí fúnra rẹ farahàn báyìí ní àgọ́ Ọlọ́pàá. Ìròyìn ń bọ lórí rẹ̀ lá��pẹ́ ẹ fojú sọ́nà Òòlù ìdájọ́ ré bá Fúnkẹ́ Akíndélé àti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn, owó ìtánràn, ìgbélé tipátipá, iṣẹ́ ìsìnlú bíi bọ̀kílẹ̀ àfojúdi . Fẹ́mi Akínṣọlá Read the full article
0 notes
Text
Ọ̀nà Jìbìtì
Bi ara ipede Radio Naigeria O.Y.O ni aye atijo, won ni, “Ifunra loogun agba, pasa ko funra, o ja sina, aja ko funra, aja jin, ti onile naa ko ba funra, ole ni yoo ko lo”. Eyi ni o difa fun gbogbo awa ti a maa n gbe moto lo si ibi inawo. Ara iwa jibiti ibe ni ki awon kan lo ba adari eto ti gbogbo eniyan mo si M.C. Won a ni ki o polongo nomba moto jade, ki eni to nii le wa tun wa si ibi to dara. Igba ti eni naa ba de ibe lo maa dede ri awon kan ti won ti go dee pelu ibon. Won si maa ni ki o ko gbogbo owo ati awon nnkan miiran to ba lowo lori fun awon loju ese. Opo to ba se agidi maa n sabaa fara gba ogbe ti won ko ba ba isele naa lo. Iwe IROYIN OWURO wa n gba wa niyanju pe ti iru ikede bee ba sele, ki onimoto ma tete lo, ti o ba si lo ki o ma se da lo. E ma se je ki a dabii “f’Olorunso to n fokun ogede gope”. Read the full article
0 notes
Text
Omijé bọ́ lójú ù mi nígbà tí mo rí olóògbé Pa Kasumu gbẹ̀yìn.—Olóyè Lere Pàímọ́
Omijé bọ́ lójú ù mi nígbà tí mo rí olóògbé Pa Kasumu gbẹ̀yìn.—Olóyè Lere Pàímọ́ Bá a pẹ́ tí tí, bí ẹni rebi,bi èmi sì gùn gùn gùn bí okùn tó gùn,ikú lòpin èèyàn. Ìjọ aláyé ti dáyé, lakásọlérí ti í ṣunkún ara a wọn, kò ṣẹ́ni tí ò níí kú, kò ṣẹ́ni tí oko baba rẹ̀ kò ní dìgbòrò. Ìlúmọ̀ọ́ká àgbà ọ̀jẹ̀ nídìí iṣẹ́ tíátà, Lere Paimọ ti sàlàyé pé lọ́pọ̀ ìgbà, àìrìríjẹ́, àìrímú tàbí ìrònú má a ń jẹ́ kí ọjọ́ ogbó dagun. Lásìkò tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ikú tó pa àgbà ọ̀jẹ̀ nínú tíátà míràn, Pa Kasumu, Paimọ ní ó yẹ kí àgbàlagbà máa rí àánú gbà, láti ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn àwùjọ, kìí ṣepé èèyàn ń tọrọ. Àgbà ọ̀jẹ̀ nínú isẹ tíátà náà ní omijé bọ́ lójú òun nígbà t’óun rí olóògbé náà gbẹ̀yìn, nitori ipo to wa. Ó wá se àdúrà pé kí Aláwùràbí dí ẹbí tí olóògbé náà fi sílẹ̀ mú, kí Ọlọ́run forí jin òkú. Nínú ọ̀rọ̀ tí ẹ̀, Salami sàlàyé pé ènìyàn tó ṣe é mú yangàn ni Pa Kasumu nígbà ayé rẹ̀, o si tún jẹ́ ẹni tí ó máa ń tèlé òfin àti ìlànà iṣẹ́ rẹ. Ọga Bello tẹ̀síwájú pé “Ó bani níńú jẹ́ sùgbọ́n kò sí nǹkan tí a le ṣe sí àṣẹ Ọlọ́run. Saájú àsìkò yìí ni a ti ń sàfẹ́rí Pa Kasumu nítorí ó ti tó ọdún díẹ̀ sẹ́yìn tí kò ti lè darapọ̀ mọ́ wa mọ́ láti ìgbà tí ó ti ṣe àìsàn” “Àdúrà mi ni pé kí Ọlọ́run tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere, kí ó sì tu àwọn ẹbí olóògbé nínú” Toyin Adewale, Jaiye Kuti, Toyin Adegbola àti Yomi Fabiyi naa wà lára àwọn òṣère tí o ti ń ṣe elédè lẹ́yìn rẹ Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Fabiyi ní “Ẹni iyì àti ẹ̀yẹ ni Pa Kasumu tí mo sì ní ìfẹ́ rẹ̀ gídí, mò ń ṣelédè lẹ́yìn rẹ̀ fún iṣẹ́ ribiribi tó ṣe nínú iṣẹ́ tíátà.” Ní ti Toyin Adegbola, Ó ní “O dárọ Kayode Odumosu, kí Ọlọ́run dẹlẹ̀ fún, kí ó sì tẹ sí afẹ́fẹ́ rere. Foluke Daramola- Salako ló kéde ikú Pa Kasumu lórí àtẹjiṣẹ́ instagram rẹ, gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, Kayode Odumosu kú ní ilé ìwòsàn kan ní Abeokuta lásìkò àisan ranpẹ. Fẹ́mi Akínṣọlá Read the full article
0 notes
Text
Àmọ̀tẹ́kùn: Ẹ̀ṣọ́ ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) ‘Àmọ̀tẹ́kùn’ ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ káàkiri ilẹ̀ káàárọ̀ o ò jíire
Ẹ̀ṣọ́ ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) ‘Àmọ̀tẹ́kùn’ ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ káàkiri ilẹ̀ káàárọ̀ o ò jíire. Àmọ̀tẹ́kùn Ọ̀rọ̀ ti di olójú ò níí yajú ẹ̀ sílẹ̀ kí tàlùbọ̀ ó yíwọ̀ọ́ àti pé ọmọ onílùú kò níí fẹ́ ó tú lọ̀rọ̀ dà báyìí ó, bí. Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Kayode Fayemi ti kéde pé gbogbo ètò ti tò báyìí fún Ilé iṣẹ́ ètò ààbò ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) ”Àmọ̀tẹ́kùn”” láti bẹ̀rẹ̀. Fayemi ní ọjọ́ kẹsàn án, oṣù kínní, ọdún 2020 ni ètò náà táwọn gómìnà mẹ́fà apá gúúsù orílẹ̀-èdè- Nàìjíríà ìwọ̀ oòrùn ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ yóó bẹ̀rẹ̀ káàkiri ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá). Gómìnà Fayemi fi ọ̀rọ̀ ọ̀hún léde nínú ọ̀rọ̀ ọdún tuntun tó báwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Èkìtì sọ L’ọ́jọ́rù, ọjọ́ kínní, oṣù kínní, ọdún 2020. Fayemi ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ‘Àmọ̀tẹ́kùn”’ yóó máa ṣe ìrànwọ́ fún àwọn agbófinró ní gbogbo ìpínlẹ̀ mẹ́fà nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá). Gómìnà Èkìtì ní Ìjọba ti setán láti ríi pé ètò ààbò gbópọn síi nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá). Ó ní lóòtọ́ọ́ ni pé ìwà ọ̀daràn kò le tán nílẹ̀ pátápátá, à mọ́ àwọn gómìnà mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ti fẹnu kò láti ríi pé ìwà ọ̀daràn dínkù káàkiri ilẹ̀ káàárọ̀ o jíire. Àmọ̀tẹ́kùn Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ OPC àtàwọn ẹgbẹ́ ajìjàgbara míì nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá) ti ké pe àwọn gómìnà yìí tẹ́lẹ̀ pé kí wọ́n fáwọn láṣẹ láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn agbófinró láti gbógun ti àwọn jàǹdùkú tó ń dá rògbòdìyàn sílẹ̀ nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá). Fẹ́mi Akínṣọlá 📸South-West Nigeria🇳🇬 launch security outfit 'Amọtẹkun' (The Leopard). pic.twitter.com/IJEebfZ4Oi— Kayode Ogundamisi (@ogundamisi) January 3, 2020 Read the full article
0 notes
Text
Ìdí tí a fi yọ Donald Trump nípò Ààrẹ
Alágbára ayé,alágbára ayé,a sè a ṣẹ̀ má lù kan, Ọlọ́run o tíì da sí dúníyàn .Bí nǹkan se n lọ yìí, Donald Trump ni Ààrẹ orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà kẹta nínú ìtàn tí ọ̀bẹ yóó bá ń dìí láti ọ̀dọ̀ àwọn Ilé aṣojú-ṣòfin lórílẹ̀-èdè náà. Ìgbésẹ̀ yìí ti wá sọ ọ́ di kannakánná na ọmọ ẹ̀gà bayii nígbà tí ìjíròrò láti buwọ́lu ìyọnípò náà bá wáyé ní Ilé aṣòfin àgbà níbẹ̀. Ẹ̀sùn méjì tó dá lórí àsìlò ipo, ati ṣiṣe idiwo fún iṣẹ́ Ilé aṣòfin-ni wọ́n fi kan Ààrẹ Donald Trump . Ìdìbò lórí ẹ̀sùn méjì yìí kò ṣàì bá Ìlànà ẹgbẹ́ òsèlú lọ. Gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú Democrats yàtọ̀ sí méjì ló dìbò fún yíyọ Trump nípò, bẹ́ẹ̀ ni àwọn Republicans tó jẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú Trump dìbò takò ó. Wákàtí mẹ́wàá gbáko ni ìjíròrò lórí ọ̀nà tí Ìlànà ìyọnípò náà yóó gbà fi wáyé láàrin àwọn aṣòfin àgbà náà ní Amẹ́ríkà. Ní nǹkan bíi agogo méjì àbọ̀ òru òní tó jẹ́ agogo mẹ́jọ ààbọ̀ alẹ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọn buwọ́ lu ìdìbò náà. Ẹ̀sùn àsìlò ipò tí wọ́n fi kan Ààrẹ Trump dá lórí ẹ̀sùn pé ó gbìyànjú àti fún orílẹ̀èdè Ukraine lókùn lọ́rùn kí ó leè kéde ìwádìí ọ̀kan lára àwọn alátakò rẹ̀ lẹ́gbẹ́ òsèlú Democrats, alàgbà Joe Biden. Ẹ̀sùn kejì tó kọ́ Trump lẹ́sẹ̀ ni pé ó dí Ilé aṣòfin lọ́wọ́ iṣẹ́ nípa kíkùnà láti fọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé náà lórí ètò ìwádìí àti yọ Àrẹ náà nípò pẹ̀lú pípàṣẹ pé kí àwọn má ṣe fara hàn jẹ́rì í níwájú Ilé náà. Igba ó lé ọgbọ̀n, 230 àwọn aṣòfin ló dìbò kí wọ́n yọ ọ́ lórí ẹ̀sùn àsìlò ipò tí àwọn mẹ́tàdínnígba, 197 sì ta kò ó. Igba ó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ló dìbò fún ẹ yọ Trump lábẹ́ ẹ̀sùn pé ó dí Ilé aṣòfin lọ́wọ́ tí àwọn méjìdínnígba sì ta kò ó. Pẹ̀lú ìyọnikúrò nípò rẹ̀ yìí, Donal trump ti di ṣàwáwù kan náà pẹ̀lú àwọn Ààrẹ méjì mìíràn tó ti jẹ rí nílẹ̀ Amẹ́ríkà nínú ìtàn orílẹ̀èdè ọ̀hún-Andrew Johnson àti Bill Clinton. Èyí ti fa ìjíròrò àti ìgbẹ́jọ́ gbogbo di iwájú àwọn aṣòfin àgbà lórílẹ̀-èdè náà láti mọ̀ bóyá lóòótọ́, Trump yóó fi ipò sílẹ Fẹ́mi Akínṣọlá http://iroyinowuro.com.ng/ Read the full article
0 notes