#ooduarere.com
Explore tagged Tumblr posts
Text
Èsì àyẹ̀wò tuntun Nàìjíríà fihàn pé “313” èèyàn ti gbàlejò Kofi 19 …àjọ NCDC
Èsì àyẹ̀wò tuntun Nàìjíríà fihàn pé “313” èèyàn ti gbàlejò Kofi 19 …àjọ NCDC À fi kí á bẹ Ọlọ́run kó bá wa dásí ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn ajániláyà pàtì yìí, bí àwọn tó ní kòrónáfairọ̀ọ̀sì ní Nàìjíríà ti ń peléke sí i báyìí,lẹ́yìn tí àjọ NCDC tún kéde okòólélọ́ọ̀dúnrún dín méje èèyàn tí èsì àyẹ̀wò wọn sẹ̀sẹ̀ jáde. Ní báyìí, èèyàn ẹgbẹ̀rún méje, àti . òjìlélẹ́gbẹ̀rin dínkan (7839) ni àkọsílẹ̀ wà pé ó ti ní àrùn náà ní Nàìjíríà. Àkójọpọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ tí èsì tuntun náà ti wá nìyí. Àjọ tó ń mójútó àjàkálẹ̀ arun l’órílẹ̀èdè Nàìjíríà, NCDC, kéde pé ènìyàn igba àti márùndínláádọ́rin ni àyẹ̀wò fihàn pé ó tún ní àrùn ni apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì Naijiria. Nínú èsì àyẹ̀wò náà, ìpínlẹ̀ Èkó ní èèyàn mẹ́taleláàdóje, Ọ̀yọ́ ní mẹtàlélọ́gbọ̀n, Edo sì ní méjìdínlọ́gọbn. àwọn tó ti ní l’órílẹ̀èdè Nàìjíríà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́r��ndinlọ́ggbọ̀n (7526). Ẹgbẹ̀rún méjì àti mẹ́rìnléláàdọ́sàn (2174), ti rí ìwòsàn, okòólérúgba lé kan (221) sì ti kú. Fẹ́mi Akínṣọlá Read the full article
0 notes
Text
Ènìyàn 148 míràn lárùn Covid-19 ní Nàìjíríà–Àjọ NCDC
Ènìyàn 148 míràn lárùn Covid-19 ní Nàìjíríà–Àjọ NCDC Ó ti pé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti márùndínládọ́jọ èèyan tó ti ní àrùn apinni léèmí yìí ní Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Èkó ló ṣì ń léwájú. Ní bí a ṣe ń kó ìròyìn yìí jọ. Iye àwọn tí àyẹwò ti fihàn pé wọ́n lárùn apinni léèmí coronavirus lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó dín àádọ́ta èèyàn báyìí. Àjọ NCDC ló ṣàlàyé ẹ̀kúnrẹ́tẹ́ èyí nínú ìkéde alálàálẹ̀ tí wọ́n máa ń ṣe láti sọ ibi tí iṣẹ́ dé dúró lórí ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kofi 19 lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Èkó ló ń léwájú lókè téńté àtẹ. Àwọn onímọ ètò ìlera kò sawun òótọ́ ọ̀rọ̀ náà pé, ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé nítorí pé ìpínlẹ̀ Èkó ni ètò àyẹ̀wò rẹ̀ pọ̀jù lọ, ló fa èyí, bákan náà ni Ìpínlẹ Kano náà ti gòkè tẹ̀le pẹ̀lú ìbẹ̀rẹ̀ ètò àyẹ̀wò níbẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye tó wọ tọ ikú ọ̀wọọwọ̀ọ́ àti àìsí ìtọ́jú àti amójútó tó péye fún àjàkálẹ̀ àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ ọ̀hún tó mú ibùdó síbẹ̀ . Fẹ́mi Akínṣọlá Read the full article
0 notes
Text
Ọ̀ọni ilé ifẹ̀ bẹ̀rẹ̀ fínfín ìtagbangba ní Ifẹ̀
Ọọ̀nirìṣà ilé Ifẹ, jìngbìnì bí àtẹ àkún,Ọba Adéyẹyè Ẹnitan Ogunwusi bẹ̀rẹ̀ fínfín àwọn ìta gbangba gbogbo ní ìlú Ilé Ifẹ̀ lẹ́yìn tó kéde ríra àwọn ohun èlò afínko láti dẹ́kun ọwọ́jà àrùn apinni léèmí COVID-19. Ọba Adéyẹyè ra àwọn irin���ẹ́ afínko tí wọ́n ṣe lábẹ́lẹ́ tí owó rẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́jọ náírà láti ṣe ìrànwọ́ fún ìgbésẹ̀ Ìjọba lórí wíwa wọ́ àrùn apinni léèmí Coronavirus bọlẹ̀. Kábíyèysí Ọọ̀nirìṣà kò ṣàì tẹnumọ́ pàtàkì fínfín àwọn ìta gbangba gbogbo káàkiri ìlú, ìpínlẹ̀ àti jákèjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Read the full article
0 notes
Text
Pa Kasumu, ó dìgbà kan ná
Kayode Odumosu,papòdà lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rin Gbajúgbajà òṣèré tíátà Kayode Odumosu tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Pa Kasumu ti juwọ́ ìgbẹyìn sáyé pé ó dìgbàkan. ”Èèyàn dáadáa ni wọ́n yàtọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ òṣèré tíátà.Ikú wọ́n jẹ́ eléyìí tó fi ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lẹ́mìí” Yàtọ sí Mr Latin àwọn òṣèré míràn bí Foluke Daramola ti fi ìkéde ikú Pa Kasumu sí ojú òpó wọn ní Instagram pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìkẹ́dùn ikú rẹ̀. Ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Kẹta ọdún 1953 ni wọ́n bí Kayode Odumosu ní ìlú Ìbàdàn. Ọmọ Odogbolu ní ìpínlẹ̀ Ogun ni a gbọ́ pé Bàbá rẹ̀ jẹ́ tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ Abeokuta. Ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀ eré sinimá tí àwọn ��èyàn sì mọ́ ọ̀ gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtarìgì nínú awọn adẹrinposonu eré tíátà lédè e Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́ṣì. Lọ́jọ́ Àìkú ní Ààrẹ àwọn òṣèré tíátà Yorùbá ní Nàìjíríà Bolaji Amusan Mr Latin fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn. Ó ti tó ọjọ́ mẹ́ta tí àìsàn ti ń bá Pa Kasunmu fínra,k kí ó tó wá já sí t’ọlọ́jọ́. http://iroyinowuro.com.ng/2020/03/02/pa-kasumu-o-digba-kan-na/ Read the full article
0 notes
Text
Ilé-ẹjọ́ fi mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà fa APC létí
Ilé-ẹjọ́ fi mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà fa APC létí Ejo ti ile-ejo giga to fi ikale si ilu Abuja da ni ojo ketala, osu yii ni egbe oselu APC ni awon ko fara mo. Eyi ko tii saba waye ri ni orileede yii, ki ile-ejo giga da ejo ki awon kan wa ni won ni lati tun se ayewo re. Ejo naa lo fagi le ibo to gbe David Lyon wole gege bi gomina ipinle Bayelsa labe egbe oselu APC. Awon egbe PDP ni won pejo pe iwe eri igbakeji gomina naa ko moyan lori rara. Won ni orisiirisii oruko lo wa lori iwe eri igbakeji gomina naa, iyen Seneto Biobarakuma Degi-Eremienyo. Ile ejo ni ki awon to ni ejo ko te awon lorun fa asise awon jade sugbon ko si agbejoro to le fa asise Kankan jade ninu ejo naa. Eyi mu ki ile-ejo giga naa fi milionu mewaa naira fa egbe APC leti. Ile-ejo ni ki won ma se je ki iru re waye mo. Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí Read the full article
0 notes
Text
Kò sí ilé tàbí só̩ò̩bù tí a kò le fo̩ láti ké̩rù òfin – Àjo̩ Customs
Awon ajo asobode ile Nigeria ti gbogbo eniyan mo si Customs ni won n ba awon oniroyin soro ni ipinle Adamawa pe, ko si ile tabi soobu ti awon ko le ja tabi fo ti o ba ye. Won ni gbogbo eda tabi onisowo fayawo ti awon ba kefin pe o keru wole lona aito ni awon le fagidi ja ile tabi soobu re ki awon si lo awon ero ofin naa lo. Gege bi iko ti Ogbeni Kamarudeen Olumon dari ni ipinle Adamawa se salaye. O ni bi awon se n ge awon onifayawo lowo ni won n bo oruko. O ni gbogbo ogbon alumokoroyi ni won mo ti won si fi n koja wole. O ni ofin abala 147 ajo Customs gba awon laaye lai gbase lati ibikankan lati lo ko iru oja bee. Awon ara oja Mubi ni ipinle naa rawo ebe si ijoba apapo ki o jowo si oju aanu wo awon nitori pe opo onisowo lo dawojo lati lo ra oja ti awon ajo naa gbese le. Won ni awon ko tun je fi iru aso bee seegun mo. Awon ajo yii ko gbo ebe rara, gbogbo iresi, ororo ati awon nnkan ile okeere miran ti won ba ninu oja Mubi naa ni won ko. Yinka Alabi Read the full article
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/about-isefa-itefa-idafa-ise-ifa/
About Isefa, Itefa, Idafa, Ise Ifa/Akose.
Isefa is to receive one hand of Ifa. This only happens if due to one reason or the other, the person could not be initiated at that present time and it’s important for such person to have Ifa at that time so such person will receive one hand of Ifa.
Also it’s done where by Ifa instructed that a new born needs to have Ifa immediately, one hand of Ifa will be made for such baby.
Itefa: this is the complete process of Ifa initiation. Such person enters Igbodu, cut hair and every other rites are done accordingly.
Idafa: this simply means Ifa consultation, the process of seeking clarification on things we couldn’t not understand from Ifa through a competent Babalawo.
Ise Ifa/Akose: these are works that comes after Ebo and it’s done only if it is requires by that Odu. It’s done to ease all that has been done for the betterment of the person who went for consultation. Akose could be for financial stability, victory, favor and so on.
Akose is also done even without consultation. These are part of the scientific aspect of Ifa where nature comes to play an important role with the use of leafs. Roots, water, seeds and all aspect of nature comes together to perform wonders for man’s purpose.
It’s important to note that doing Itefa/Isefa doesn’t mean you will automatically have all the wealth in this world but rather Ifa promised one thing that such person will never lack.
It doesn’t mean you won’t face challenges and obstacles but be rest assured that you will always be victorious. Aboru Aboye. ~ Owomide
2 notes
·
View notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/eemo-iyawo-afesona/
Èèmọ̀ rè é o !, Ìyàwó àfẹ́sọ́nà kú sínú Kànga, nígbeyàwó kọ̀la
Èèmọ̀ rè é o !, Ìyàwó àfẹ́sọ́nà kú sínú Kànga, nígbeyàwó kọ̀la
Èèmọ̀ rè é o !, Ìyàwó àfẹ́sọ́nà kú sínú Kànga, nígbeyàwó kọ̀la
Fẹ́mi Akínṣọlá
À fi ká kún f’áàdúà kí ọjọ́ ayọ̀ ẹni ó má padà dọjọ́ ìbànújẹ́.Kí èṣù ó sì má ráàyè gbọjọ́ ẹ̀yẹ ẹni . À bí kín ni ká ti pe ti ọ̀dọ́mọbìnrin ọmọ ọdún mérìndínlógún kan, Fatima Abubakar tó pàdánú ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tó ré sínú kànga omi nígbà tí ìgbéyàwó rẹ̀ ku ọ̀la.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà la gbọ́ pé ó wáyé ní ìlú Gajaja, ìjọba ìbílẹ̀ Danbatta, nìpínlẹ̀ Kano.
Bàbá Fatima, Ọ̀gbẹ́ni Abubakar sọ fún akọ̀ròyìn pé, ìṣẹ̀lẹ̀ àgbọ́gbárímú náà wáyé lásìkò tí ọmọbìnrin náà àti àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ ń lọ fún ayẹyẹ alẹ́ omidan nílé àǹtí rẹ̀ kan l’ọ́jọ́rùú.
“Ń ṣe ló dúró l’ẹ́gbẹ̀ ẹ́ kànga náà, kó tó di pé ó fi ẹ̀sẹ̀ kọ, tó sì ṣubú sínú kànga.
Ọjọ́ kejì, tó jẹ́ Ọjọ́bọ ló yẹ kí ayẹyẹ ìgbéyàwó láàrin òun àti ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀ ó wáyé.
Bàbá Fatima ṣàlàyé pé, inú ọmọ òun dùn sí ìgbéyàwó náà, àti pé Ifẹ̀ wà láàrin òun àti ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀.
Ó sọ pé ó ṣeni láànú pé inú ìbànújẹ́ ni àwọn àlejò tó yẹ kó wá bá òun yọ̀ ayọ̀ ìgbéyàwó ọmọ òun wà báyìí.
Inú ìbànújẹ́ ni ọkọ àfẹ́sọ́nà náà wà, tí kò sì le bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀.
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/opo-eeyan-lo-sa-fun/
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sá fún mi nígbà tí mo dùbúlẹ̀ àìsàn…Taiwo Hassan
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sá fún mi nígbà tí mo dùbúlẹ̀ àìsàn…Taiwo Hassan
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sá fún mi nígbà tí mo dùbúlẹ̀ àìsàn…Taiwo Hassan, Ògògó
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà ní bí ẹyìn ọ̀rọ̀ ò bá ì pọ́n, ẹnìkan kìí sí i ,bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí bí gbajúgbajà òṣèré sinimá àgbéléwò,n nì, Taiwo Hassan tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ògògó ti padà ṣọ̀rọ̀ lori àárẹ̀ tó ṣe é fún odindin ọdún mẹ́jọ láti ọdún 2004 títí di 2012.
Nigba ti o n ṣe aisan naa, oriṣiriṣi iroyin ofege lo gbalukan nipa nnkan to n ṣe oṣere naa.
Nigba ti awọn kan n sọ pe o ni arun HIV ni awon kan ni egbo igi oloro lo tu sii ninu. Ṣùgbọ́n àgbà ọ̀jẹ̀ òṣèré náà ti ṣàlàyé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ síi nígbà náà fún aráyé
Ògògó ní nínú ààwẹ Ramadan ọdún 2004 ni òun mọ̀ pé òun ní àrùn ọgbẹ́ẹnú tí wọ́n pé ní “Ulcer”.
Ó ní òun lò tó oṣù méje tí òun ń kí ìrun lórí ìjókòó nítorí pé òun kò tó ẹrù Ọlọ́run tó ń dìde dúró láti kí ìrun.
Ògògó ní òun ní láti pa ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ òun nígbà tíròyìn ń káàkiri pé òun gbé egbòogi olóró ni àbí pé òun kó àrùn HIV ni.
T’ònti pé ẹlẹsin Muslumi, Kristẹni àti ìṣẹ̀ṣe ń gbàdúrà fún un, àwọn orẹ àti ìyàwó rẹ̀ padà fi sílẹ̀ lọ nígbà tí ìṣòro náà pọ̀.
Ògògó ní òun padà fẹ́ obìnrin tó dúró ti òun nígbà ìṣòro náà, obìnrin náà sì ti bímọ méjì fún òun báyìí.
Ṣé obìnrin kúkú kọ́kọ́ bímọ fún ni kò pé kó dúró ti ni nígbà ìṣoro .
Taiwo Hassan gba àwọn tó bá ń la ìṣòro kan kọjá lásìkò yìí láti túbọ̀ súnmọ́ Ọlọ́run kí wọ́n kún fún àdúrà.
Ó ní kò sí ìṣòro tó ní ìbẹ̀rẹ̀ tí kò ní lópin tí èèyàn bá ní sùúrù tó dẹ̀ ń gbàdúrà.
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/i-love-oodua-wins/
I love Oodua wins
A poll between I love Yoruba or I love Oodua took place and latter won by a large margin. Ooduarere.com favourite cap on Twitter profile pic and facebook will be replaced with I love Oodua. Other social media profile picture will be replaced later and this page will be updated each time.
Ooduarere.com
Before and after profile picture of Ooduarere.com Twitter page.
Before and after profile picture of Ooduarere.com Facebook page.
Before and after profile picture of Ooduarere.com Instagram page.
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/oodua-wins/
Oodua wins
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/ojo-ibi-ogota-odun-ogogo/
Ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún, Ogogo.. ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ eré bọ́lùú wáyé
Ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún, Ogogo.. ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ eré bọ́lùú wáyé
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà Yoruba to tí ta gbòǹgbò káàkiri àgbáyé ni Alhaji Taiwo Hassan tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ogogo ọmọ kúlódò jẹ́. Nítorí náà kò ya ni lẹ́nu nígbà tí ètò lónírúurú gbode kan fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún tó ṣe. Lára àwọn ètò náà ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàrin ikọ̀ ogogo, (Ogogo All stars) àti ikọ̀ to jẹ́ ti olórí Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko, ( Obasa All stars). àá áà àà éé èè ẹ́ ẹ́ẹ̀ù ùẹ̀ ùẹ̀ ẹ̀ẹ̀ íí ìì óó òò ọ́ọ́ ọ̀ọ̀ ọọ úú ùù àà Nígbà tí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà yóó fi parí ní pápá ìṣeré Agége, góòlù méjì làwọn ikọ̀ Obasa All Stars fi gbẹyẹ mọ́ ikọ̀ Ogogo lọ́wọ́ o.
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/local-news/ilee%e1%b9%a3e-dss-tu-sowore-sile/
Iléeṣẹ́ DSS tú Sowore sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ gbọọrọ ní àhámọ́
Iléeṣẹ́ DSS tú Sowore sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ gbọọrọ ní àhámọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn òṣìṣẹ́ DSS gbé Soworẹ lásìkò tí ó fi ń léwájú ìwọ́de “Revolution now”. Ìtúsílẹ̀ rẹ̀ ń wáyé lẹ́yìn tí ó ti lo ọjọ́ márùndíláàdóje ní hàhámọ́ àwọn DSS.
Onírúurú ìdájọ́ ló ti wáyé èyí tí àwọn Ilé ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ní kí wọ́n fi sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ DSS kọ̀ jálẹ̀ pẹ̀lú onírúurú àwáwí. Àmọ́sá ni ọjọbọ ni ileẹjọ miran tun pa aṣẹ ki iléeṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS ó tú u sílẹ̀ láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógún
Ìrètí wà pé yóó tún farahàn ní Ilé ẹjọ́ ní ọjọ́ Ẹtì nítẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀.
Ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹjọ ọdún 2019 ni àwọn agbófinró DSS lọ gbé Ọmọyẹle Soworẹ lórí ẹ̀sùn pé ó ń ṣagbátẹrù àwọn ìwọ́de “Revolution now” eléyìí tó ń bèèrè fún ìṣèjọba rere lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní kẹfa oṣù Kọkànlá ni ọ̀gbẹ́ni Soworẹ kọ́kọ́ mú ìlérí béèli àkọ́kọ́ tí Ilé ẹjọ́ fún ṣẹ ṣùgbọ́n tí iléeṣẹ́ DSS kò túu sílẹ̀.
Ìgbésẹ̀ ìfisáhámọ́ Sowore ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àjọ ilẹ̀ òkèèrè àti ti Nàìjíríà pẹ̀lú láti kígbe sí Ìjọba àpapọ̀ láti bọ̀wọ̀ fún òfin ṣùgbọ́n tí iléeṣẹ́ DSS kùnà láti tú u sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àṣẹ ìṣaájú láti ilé ẹjọ́.
Bákan náà ni iléeṣẹ́ DSS tún dá Olawale Bakare náà sílẹ̀.
Àwọn méjéèjì yí ni Ìjọba àpapọ̀ ń fi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ gbàjọba kàn.
Iléeṣẹ́ DSS tú Sowore sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ gbọọrọ ní àhámọ́
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/politics/maa-%e1%b9%a3a-ipa-lati-mu-kawon/
Màá ṣa ipá láti mú káwọn aráàlú nígbẹkẹ̀lé nínú ìjọba – Seyi Makinde
Màá ṣa ipá láti mú káwọn aráàlú nígbẹkẹ̀lé nínú ìjọba
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní ,bí Ọlọ́run bá rí ọ, jéèyàn náà ó sẹ̀ríìrẹ,bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí,bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti fọwọ́ gbáyà pé òun yóó sa gbogbo ipá òun láti rí i dájú pé àwọn èèyàn rere ìpínlẹ̀ náà ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ìjọba òun.
Gómìnà Makinde fi ọwọ́ idaniloju ọ̀hún sọ̀yà nínú ọ̀rọ̀ apilẹkọ rẹ̀ níbi ìpàdé ìta gbangba lórí ètò ìṣúná ọdún 2020 tó wáyé ní ẹkùn ìdìbò ààrin gbùngbùn Ọ̀yọ́, ní gbọ̀ngàn Atiba, nílù Ọ̀yọ́. Makinde ní Ìjọba òun ti setán láti se àtúntò ìlànà ìṣèjọba, kí òun sì se àgbékalẹ̀ ìpínlẹ̀ tó lóòrìn fún ìṣèjọba alájùnmọ̀ṣe tí ìlẹ̀kùn rẹ̀ yóó sí sílẹ̀ fáwọn aráàlú.
Gómìnà Makinde. ẹni tí olórí òṣìṣẹ́ lọ́ọ́fìsì Gómìnà, Olóyè Bisi Ilaka ṣojú fún ṣàlàyé pé àfojúsùn ìpàdé ìta gbangba náà ni láti jẹ́ kí ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kọ̀ọ̀kan ní ẹnu nínú ìṣèjọba, kí Ìjọba sì le ní ìmọ̀ nípa ohun tí Ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan ń pòùngbẹ rẹ̀ nígbaradì fún àmúsẹ ètò ìṣúná ọdún 2020.
Makinde ní àfojúsùn ìjọba òun ni láti mú ètò ìlànà ìṣèjọba onídàgbàsókè tí yóó gbà tó ogún ọdún, èyí tí yóó wà fún Ìjọba mi àti àwọn ìṣèjọba tí yóó tẹ̀lé mi.
“Bákan náà ni mo tún fẹ́ mú àgbéga bá okùn àjọṣepọ̀ láàrin ìjọba àti àwọn aráàlú nípa bíbèèrè èrò wọn lórí ìṣúná ọdún tó ń bọ̀.” “Yàtọ̀ sí pé màá rí i dájú pé a lo àwọn ohun àlùmọ́ọ́ní fáwọn iṣẹ́ àkànṣe tó nítumọ̀ sí aráàlú, àti àmúsẹ àwọn ètò tí yóó mú ìlọsíwájú bá ètò ìlera àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ yìí, máa tún tiraka láti rí i dájú pé aráàlú ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ìjọba mi.”
Ṣaájú nínú ọ̀rọ̀ i ìkínni káàbọ̀ rẹ̀ Kọmísánà fétò ìṣúná àti ààtò ọ̀rọ̀ ajé nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́, Amòfin Adeniyi Farintọ mẹ́nubàá pé ìpàdé ìta gbangba náà se kókó nítorí ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí Ìjọba kan àti àwọn aráàlú yóó jókòó papọ̀ láti jíròrò lórí ètò ìṣúná kan kí wọ́n tó gbé e kalẹ̀. Farintọ ní Ìjọba Seyi Makinde yóó tẹ̀síwájú láti máa kó àkóyawọ́ láì fi igbá kan bọ ọ̀kan nínú, nínú àwọn ìlànà tó bá gbékalẹ̀, tí yóó sì máa gba èrò aráàlú láàyè.
Nígbà tó ń dáhùn sí àwọn ìbéèrè aráàlú lásìkò ìjíròrò náà, Makinde sèlérí pé òun yóó pèsè ojú ọ̀nà tó já gaara sí ẹkùn ìdìbò náà. Ó ní òun yóó tún se àgbékalẹ̀ ẹ̀ka àjọ tó ń se àtúnṣe ojú ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, OYSTROMA sí ẹkùn náà pẹ̀lú bí àfikún se bá owó t’íjọba ìpínlẹ̀ náà ń gbà láti ọ̀dọ̀ ọ Ìjọba àpapọ̀ pẹ̀lú bílíọ̀nù márùn náírà.
Lórí ọ̀rọ̀ LAUTECH, Makinde ní wọ́n ti gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ láti ṣiṣẹ́ lórí bí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóó se gba àkóso Ilé ẹ̀kọ́ Fásitì Ladoke Akintola tó wà nílùú Ogbomọsọ pátápáta.
Màá ṣa ipá láti mú káwọn aráàlú nígbẹkẹ̀lé nínú ìjọba – Seyi Makinde
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/ore-falomo-irunmole-i%e1%b9%a3egun/
Ọrẹ Fálọmọ , Irúnmọlẹ̀ Ìṣègùn Tó Dáńtọ́ Nínú Ìràn Oòduà(Yorùbá) Wọ Káàlẹ̀ Lọ
Ọrẹ Fálọmọ , irúnmọlẹ̀ ìṣègùn tó dáńtọ́ nínú ìràn Oòduà(Yorùbá) wọ káàlẹ̀ lọ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Hùn! Báakú làá dère,èèyàn ò sunwọ̀n láàyè. Ni báyìí, gbogbo ọmọ Oòduà(Yorùbá) ló tí ń sun rárà ọlọ́kan ọ̀ jọ̀kan lẹ́yìn in Dókítà Ọrẹ Fálọmọ tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí oníṣègùn M.K.O Abíọ́lá nígbà ayé rẹ̀. Adarí ẹgbẹ́ Afenifẹre Ayo Adebanjọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sàlàyé pé iṣẹ́ ribiribi ní Ore Fálọmọ ti ṣe nínú ìràn Oòduà(Yorùbá), àti pé ìran Oòduà(Yorùbá) ti sọ ògo ńlá kan nù. Adebanjọ fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí gbogbo ìran Oòduà(Yorùbá) jí gírí láti gbé ògo ìran rẹ̀ ga bi Ọrẹ Fálọmọ ṣe se nígbà ayé rẹ̀, papàájùlọ gẹ́gẹ́ bíi Dókítà Abiola, ó dúro ti Abíọlá gidigidi lásìkò ìsòro, kò kẹ̀yìn sí bí àwọn tó kù ṣe ṣe nígbà náà.
Ó fí kún-un pé àwòkọ́se rere ni Fálọmọ jẹ́ nígbà tó fi jẹ́ Ààrẹ àwọn ẹgbẹ́ Dókítà ní Nàìjíríà, àmúyangàn ni àsìkò rẹ̀ jẹ́ fún ìdarí rẹ̀ àti ipò tí ọ̀rọ̀ ìlera wà lásìkò náà. Afẹnifẹre ní Dókítà Fálọmọ kìí ṣe ẹni tí ìràn Oòduà(Yorùbá) gbọdọ̀ gbàgbé ní kíákíá.
,A bí Dókítà Oluwatamilore Fálọmọ lọ́jọ́ kẹrin oṣù kẹsàn-án ọdún 1942 nílùú Minna tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Niger báyìí. Ọ̀gbẹ́ni Fálọmọ lọ ilé ìwé alákọ̀bẹ̀rẹ̀ ní Baptist Primary School, ìjàyè láàrin ọdún 1948 si ọdún 1955. Ilé ìwé girama Methodist Boys High School ní ìpínlẹ̀ Eko ni Fálọmọ lọ láàrin ọdún 1956 sí ọdún 1960. Fálọmọ tẹ̀síwájú ẹkọ rẹ̀ nílé ìwé St. Andrew College, nílùú Dublin lórílẹ̀-èdè Ireland láàrin ọdún 1961 sí 1962 kí ó tó lọ kàwé ní “Royal College of Surgeons ní Ireland” láti ọdún 1962 sí 1968.
Ó tún padà sí ilé ìwé “Royal College of Surgeons” nílùú Dublin lọ́dún 1978. Ọ̀gbẹ́ni Fálọmọ ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Folashade Ṣorunkẹ lọ́dún 1968.
Dókítà Fálọmọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nílé ìwòsàn Park Hospital, Davyhulme ní Manchester lọ́dún 1969 sí 1970.
Ó tún ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ètò ìlera ìpínlẹ Eko lágbègbè Surulrere lọ́dún 1971 sí 1972, kó tó lọ ṣiṣẹ́ ní Ilé ìwòsàn Ìjọba ní Ikeja lọ́dún 1972 sí ọdún 1973. Dókítà Fálọmọ di olùdarí ilé ìwòsàn Oníkòyí Clinic ní Yaba lọ́dún-un 1974 sí 1979 Fálọmọ jẹ́ Alága ẹgbẹ́ àwọn Dókítà lọ́dún 1971 sí 1974, ó tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àwọn Dókítà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì àti orílẹ̀-èdè Ireland.
Ó ṣiṣẹ́ ní Ilé ìwòsàn Maryland Specialist Hospital fún ọ̀pọ̀ ọdún. Dókítà Fálọmọ jẹ́ Dókítà fún olùdíje fún ipò Ààrẹ lábẹ́ àṣìá ẹgbẹ́ òsèlú SDP nínú ìbò Ààrẹ ọdún 1993 ní Nàìjíríà, MKO Abiola.
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/vietnamni-e-wa-oshiomole-fesi/
Vietnamni , ẹ wá dá oko ìrẹsì sílẹ̀ ní Nàíjíríà, dípò kíkórẹsì wọlé– Oshiomole fèsì ẹ̀bẹ̀
Vietnamni , ẹ wá dá oko ìrẹsì sílẹ̀ ní Nàíjíríà, dípò kíkórẹsì wọlé– Oshiomole fèsì ẹ̀bẹ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí Ìjọba Nàíjíríà se gbé àwọn ẹnu ọ̀nà àbáwọlé sí orílẹ̀ -èdè yìí tìpa ti ń mú kí orí ta àwọn lórílẹ̀-èdè tó múlé tì wá àti àwọn tó wà nílẹ̀ òkèèrè. Kódà, ìsòro yìí pọ̀ tó bẹẹ fún orílẹ̀-èdè Vietnam tó fi gbé aṣojú dìde pé kó wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ síjọba Nàíjíríà láti sí ẹnu ibodè rẹ̀ padà, kí òun leè kó ìrẹsì òun wọlé- lọ́pọ̀ yanturu.
Igbákejì Olóòtú Ìjọba Vietnam, Vuong Dinh Hue tó kó àwọn aṣojú náà wá sí Nàíjíríà ti wá ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ẹgbẹ́ òsèlú APC tó ń tukọ Ìjọba Nàíjíríà lọ́wọ́ láti báwọn bẹ Ààrẹ Muhammadu Buhari, kí ẹnu bodè wa leè di sísí padà. Ìlú Abuja ni ìgbákejì Olóòtú Ìjọba Vietnam náà ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ yìí lásìkò tó sàbẹ̀wò si Alága ẹgbẹ́ òsèlú APC nílẹ̀ wa, Adams Oshiomole lọ́fíìsì rẹ̀, tó sì tún kéde pé nítorí bí ọrọ náà se ká àwọn lára tó, àwọn yóò tún lọ dírẹ̀ẹ́bẹ̀ níwájú igbákejì Ààrẹ, Yẹmi Ọsinbajo lórí rẹ̀ pẹ̀lú.
Nígbà tó ń kí àwọn àlejò rẹ̀ kaabọ sílẹ̀ yìí, tó sì ń fèsì lórí ìbéèrè wọn, Adams Oshiomole ní àrè kò sèlú, kí wọ́n má fìse hàn wá ní Nàíjíríà nítorí báyìí ni n ó se nǹkan mi kò leè yípadà,bÍ ohun gbogbo tilẹ̀ padà.
Oshiomole ni lórílẹ̀-èdè Nàíjíríà kò leè dáhùn sí ẹ̀bẹ̀ wọn láti sí ẹnu bodè wa, tó sì rọ àwọn aṣojú ilẹ̀ Vietnam pé kí wọ́n wá gba ilẹ̀ sorilẹede Nàíjíríà láti dá oko ìrẹsi ni yóò pé wọn.
Ó ní ọmọjá ti kúò niye tí wọ́n ń rà á, nítorí Nàíjíríà kò ní jẹ́ ààtàn èròjà tó ti bàjẹ́ mọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè kan, tí wọ́n fẹ́ràn à tí máa da èròjà olóró asekúpani wọn sí .
Alága ẹgbẹ́ APC fikún un pé digbí ni àgádágodo yóò wà láwọn ẹnu bodè e wa títí táwọn orílẹ̀-èdè tó múlé tì wá yóò fi bọ̀wọ̀ fún òfin to de ìbáṣepọ̀ okoòwò láàrin orílẹ̀-èdè kan sí èkejì.
0 notes