#Asa Oodua
Explore tagged Tumblr posts
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/muslims-involve-in-this-nonsense/
Muslims involve in this 'nonsense' in Osogbo: Disgracing, sad and misleading Video - Ifa Chief Priest
I saw one disgracing, sad and misleading video on YouTube today.
One Olorisa obatala from Osogbo who the Muslims claimed to have converted from Orisa worship to becoming a muslim. This happened maybe 4days ago.
Let me start by saying it’s a big shame to the Muslims involve in this nonsense in Osogbo if all that is required of you to make someone believe in your religion is to give them 5000 naira then it’s not worth it.
It was also gathered that this said fellow is also a beggar in Osogbo but widely known as Baba Olorisa and also he’s mostly categorized among the youths.
My problem now is, it was done in such a way to attack and degrade Isese at large and this is also a wake up call to all traditionalist especially we the youths.
How far can we go support one another? The only thing most of us is concerned about is our own pocket, we don’t care about a fellow brother in our community so when they make some decisions which they feel is right to escape hunger at that present time, we start to rant!
It’s not all about calling one another to go out and drink every night, check up on your brother and see if they’ve eaten.
We need to make our community accessible and more like a sanctuary for those coming in than all the useless and needless showoff we engage in everyday.
Awo ni n gb’awo n’igbowo Bi Awo o ba gb’awo n’igbowo Awo a te Awo a de Awo a ya peregede bi eti aso
It’s Awo that supports a fellow Awo If Awo failed to support a fellow Awo Awo will be disgraced Awo will be shamed Awo will tear uselessly like the tip of a cloth.
That’s my own take on the matter. Ire ooo
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/eemo-iyawo-afesona/
Èèmọ̀ rè é o !, Ìyàwó àfẹ́sọ́nà kú sínú Kànga, nígbeyàwó kọ̀la
Èèmọ̀ rè é o !, Ìyàwó àfẹ́sọ́nà kú sínú Kànga, nígbeyàwó kọ̀la
Èèmọ̀ rè é o !, Ìyàwó àfẹ́sọ́nà kú sínú Kànga, nígbeyàwó kọ̀la
Fẹ́mi Akínṣọlá
À fi ká kún f’áàdúà kí ọjọ́ ayọ̀ ẹni ó má padà dọjọ́ ìbànújẹ́.Kí èṣù ó sì má ráàyè gbọjọ́ ẹ̀yẹ ẹni . À bí kín ni ká ti pe ti ọ̀dọ́mọbìnrin ọmọ ọdún mérìndínlógún kan, Fatima Abubakar tó pàdánú ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tó ré sínú kànga omi nígbà tí ìgbéyàwó rẹ̀ ku ọ̀la.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà la gbọ́ pé ó wáyé ní ìlú Gajaja, ìjọba ìbílẹ̀ Danbatta, nìpínlẹ̀ Kano.
Bàbá Fatima, Ọ̀gbẹ́ni Abubakar sọ fún akọ̀ròyìn pé, ìṣẹ̀lẹ̀ àgbọ́gbárímú náà wáyé lásìkò tí ọmọbìnrin náà àti àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ ń lọ fún ayẹyẹ alẹ́ omidan nílé àǹtí rẹ̀ kan l’ọ́jọ́rùú.
“Ń ṣe ló dúró l’ẹ́gbẹ̀ ẹ́ kànga náà, kó tó di pé ó fi ẹ̀sẹ̀ kọ, tó sì ṣubú sínú kànga.
Ọjọ́ kejì, tó jẹ́ Ọjọ́bọ ló yẹ kí ayẹyẹ ìgbéyàwó láàrin òun àti ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀ ó wáyé.
Bàbá Fatima ṣàlàyé pé, inú ọmọ òun dùn sí ìgbéyàwó náà, àti pé Ifẹ̀ wà láàrin òun àti ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀.
Ó sọ pé ó ṣeni láànú pé inú ìbànújẹ́ ni àwọn àlejò tó yẹ kó wá bá òun yọ̀ ayọ̀ ìgbéyàwó ọmọ òun wà báyìí.
Inú ìbànújẹ́ ni ọkọ àfẹ́sọ́nà náà wà, tí kò sì le bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀.
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/should-any-man-remain-entitled/
Should any man remain entitled to be intimate with women, after flatly denying latter the power to become Ifa diviners?
Should women be allowed to practice as Ifa diviners? (Actually, what sort of stupid question am I asking? Who appointed men as the gatekeepers regulating what women should or should not do?) The proper question is this: should any man remain entitled to be intimate with women, after flatly denying women the power to become Ifa diviners?
Prof. Moyo Okediji
1906 picture of an Ìyánífá among the Ewe people.
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/local-news/ilee%e1%b9%a3e-dss-tu-sowore-sile/
Iléeṣẹ́ DSS tú Sowore sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ gbọọrọ ní àhámọ́
Iléeṣẹ́ DSS tú Sowore sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ gbọọrọ ní àhámọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn òṣìṣẹ́ DSS gbé Soworẹ lásìkò tí ó fi ń léwájú ìwọ́de “Revolution now”. Ìtúsílẹ̀ rẹ̀ ń wáyé lẹ́yìn tí ó ti lo ọjọ́ márùndíláàdóje ní hàhámọ́ àwọn DSS.
Onírúurú ìdájọ́ ló ti wáyé èyí tí àwọn Ilé ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ní kí wọ́n fi sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ DSS kọ̀ jálẹ̀ pẹ̀lú onírúurú àwáwí. Àmọ́sá ni ọjọbọ ni ileẹjọ miran tun pa aṣẹ ki iléeṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS ó tú u sílẹ̀ láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógún
Ìrètí wà pé yóó tún farahàn ní Ilé ẹjọ́ ní ọjọ́ Ẹtì nítẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀.
Ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹjọ ọdún 2019 ni àwọn agbófinró DSS lọ gbé Ọmọyẹle Soworẹ lórí ẹ̀sùn pé ó ń ṣagbátẹrù àwọn ìwọ́de “Revolution now” eléyìí tó ń bèèrè fún ìṣèjọba rere lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní kẹfa oṣù Kọkànlá ni ọ̀gbẹ́ni Soworẹ kọ́kọ́ mú ìlérí béèli àkọ́kọ́ tí Ilé ẹjọ́ fún ṣẹ ṣùgbọ́n tí iléeṣẹ́ DSS kò túu sílẹ̀.
Ìgbésẹ̀ ìfisáhámọ́ Sowore ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àjọ ilẹ̀ òkèèrè àti ti Nàìjíríà pẹ̀lú láti kígbe sí Ìjọba àpapọ̀ láti bọ̀wọ̀ fún òfin ṣùgbọ́n tí iléeṣẹ́ DSS kùnà láti tú u sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àṣẹ ìṣaájú láti ilé ẹjọ́.
Bákan náà ni iléeṣẹ́ DSS tún dá Olawale Bakare náà sílẹ̀.
Àwọn méjéèjì yí ni Ìjọba àpapọ̀ ń fi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ gbàjọba kàn.
Iléeṣẹ́ DSS tú Sowore sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ gbọọrọ ní àhámọ́
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/art/culture/photos-agogoro-eyo-sao-paulo/
Photos: Agògòrò Èyò in Sao Paulo Brazil
Oodua (Yoruba) culture and heritage is very rich. Eyo is to honour our Ancestors. I had to join the Eyo in a dance at the celebration of Egbe Omo Oduduwa in Brazil 30th November 2019 especially being a participant myself when late Oba of Lagos, Alayeluwa Oba Adeyinka Oyekan honored my late father with Eyo Awise Akano Fasina Agboola in 1975. From Araba of Oworonsoki land Lagos Nigeria
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/happy-ose-egungun-today/
Happy Ose Egúngún today to you all.
Egúngún yodà, gbogbo Awo Egúngún yodà, òtá kòleè gbé inú ilé mó Egúngún ti yodà gbogbo Awo~ Ìwòrì gósùn
Egúngún brought out a sword, all Priests and Priestesses Egúngún brought out a sword, the enemies, wicked and evil ran out of the house Egúngún has displayed his sword, all Practioners of Isese rejoice.
May the Dwellers of heaven deal ruthlessly with our detractors.
Happy Ose Egúngún today to you all.
Stay blessed
From Araba of Oworonsoki land in Brazil
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/obi-ni-n-bi-arun/
Obi ni n bi arun
Aboru Aboye Abosise.. Ifa niiiiii
Obi ni n biku Obi ni n bi arun Obi ni n bi ofo Obi ni n bi gbogbo ibi. Olodumare abawa fi obi biku, bi arun, bi ofo, bi gbogbo ajogun ibi aye wa o. Ase edumare.
Sponsored by Asa Oodua
Cola nut helps to avoid death Cola nut helps to avoid disease Cola nut helps to avoid lost Cola nut helps to avoid all kind of problems. I pray Olodumare will use Cola to take away all the problems in our life. Ase edumare.
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/asepo-to-dan-moran/
Àsepò̩ tó dán mó̩rán wa láarin èmi ati àwo̩n èèyàn O̩yo̩ – Gómìnà
Èmi àti àwọn èèyàn Ọyọ yóò máa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ológun.. Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé inú dídùn ń ni yoòbá níí mórííya àti pé yiinínú,níí jẹ́ kẹ́ni fẹ́ ṣèmìí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ rí, bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti fí èrò ọkàn rẹ̀ hàn pé, ìjọba òun àti àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò tẹ̀síwájú láti máa fọ́wọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ọmọ ogun Nàìjíríà fún ìdàgbàsókè àwùjọ.
Makinde sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó péjú síbi ayẹyẹ ìsíde ìdíje ìbọn yínyìn láàrin àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ ológun (NASAC), èyí tó wáyé ní iléeṣẹ́ ọ̀wọ́ kejì ológun ti Adekunle Fajuyi tó wà ní àdúgbò Òdogbó Ọjọọ, nílùú Ibadan.
Makinde ní ìnú òun dún fún àyẹsí tí wọ́n fún òun, àti pe, òun àti àwọn èèyàn rere ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóó túbọ̀ máa fọwọ́sowọ́pọọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ológun. ” Mo gbàdúrà pé gbogbo àwọn akópa nínú ètò náà ni yóó se àṣeyọrí, tí ètò náà yóó sì jẹ́ mánigbàgbé fún wọn ní ìpínlẹ̀ Oyo.”
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/politics/idajo-ile-ejo-ko-so/
Ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ kò sọ pàtó ẹni tó jáwé olúborí láàrín Makinde àtiAdelabu
Ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ kò sọ pàtó ẹni tó jáwé olúborí láàrín Makinde àtiAdelabu
Fẹ́mi Akínṣọlá
Kángun kàngùn Kángun, bọ́ pẹ́,bọ́ yá, ó gbọ́dọ̀ kángun síbìkan, bẹ́ẹ̀ ló súmọ́ kí ọ̀rọ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, látàrí àgbéjáde ilé ẹjọ́. Tí Ilé ẹjọ́ kan kò bá wá fìdíi ọ̀rọ̀ múlẹ̀ ní pàtó nípa ìdájọ́ ohun ta gbé lọ síwájú rẹ̀, kínni ó yẹ ká ṣe? Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nílùú Ibadan tó ń gbẹ́jọ́ láàrin Gómìnà Seyi Makinde àti akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ du ipò Gómìnà, Adebayo Adelabu ti ẹgbẹ́ òsèlú APC.
Kókó ọ̀rọ̀ tó jáde nípa ìdájọ́ tí adájọ́ ẹlẹ́ni mẹ́ta ilé ẹjọ́ náà fi lélẹ̀ ni pé àwọn fọwọ́ rọ́ ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbẹ́jọ́ ìdìbò sẹgbẹ kan ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ kò sọ ojú abẹ níkòó bóyá Makinde tàbí Adelabu ló jáwé olúborí.
Ní ti Adelabu, ń se ló ń sọ pé kí Ilé ẹjọ́ wọ́gilé èsì ìdìbò tó gbé Makinde wọle kó sì kéde òun gẹ́gẹ́ bí Gómìnà. Àmọ́ báyìí tí Ilé ẹjọ́ náà kò ì sọ bóyá òun ni Gómìnà tàbí Makinde ni, ohun tó kàn fáwọn méjéèjì ni kí wọ́n gba Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ láti yànànà ọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.
Lójú òpó Twitter, ohun tí Ilé ẹjọ́ yí sọ tí ń mú ìríwísí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá táwọn èèyàn sì ń gbìyànjú láti tú ohun tí Ilé ẹjọ́ sọ bó ṣe yé wọn mọ. Kódà àwọn kan ti ń fi ohùn ránṣẹ́ sí Ààrẹ Buhari àti ẹgbẹ́ APC pé kí wọ́n má ṣe dásí ọ̀rọ̀ náà tí wọn ò bá fẹ́ kan àbùkù
Bí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe wà báyìí,ohun tó dájú ni pé ilé ẹjọ́ kò sọ ẹni tó jáwé olúborí bẹ́ẹ̀ sì ni kó kéde pé wọn yóó tún ìbò mìíràn dì Bí a bá ní ká tẹ̀lé ọ̀rọ̀ táwọn agbẹjọ́rò olùdíje méjéèjì yí sọ báyìí, ààyè ṣì wà nílẹ̀ fáwọn láti kọrí sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ láti sọ bí iṣu ṣe kú, bọ́bẹ ṣì ṣe pá. Kókó kan ṣoṣo tó hànde lórí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ yìí ni pé Ilé ẹjọ́ gíga ló máa yanjúẹ̀.
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/egbe-awon-agbaagba-oodua/
Ẹgbẹ́ Àwọn Àgbààgbà Oòduà Ní Osinbajo Kò Gbọdọ̀ Kọ̀wé Fipò Ẹ̀ Sílẹ̀
Ẹgbẹ́ àwọn àgbààgbà Yorùbá ní Osinbajo kò gbọdọ̀ kọ̀wé fipò ẹ̀ sílẹ̀
Ẹgbẹ́ àwọn àgbààgbà Oòduà (Yorùbá) ní Osinbajo kò gbọdọ̀ kọ̀wé fipò ẹ̀ sílẹ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Èyí ò tófò, kò tófò,fìlà aráabí kù rébété, Kemi Adeoṣun lọ , orí ló kó Adebayọ Shittu yọ,tó fi rí sáa àkọ́kọ́ lò já.Ní báyìí, ó jọ n bí rẹ́kọ̀dù ìgbákejì Ààrẹ ló kàn báyìí,bí
ọ̀rọ̀ se ń bá mokó morò bọ̀ lórí aáwọ tó ń ṣẹlẹ̀ láàrin igbákejì Ààrẹ, Yemi Osinbajo àtawọn kan nílé iṣẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà. Ẹgbẹ́ àgbààgbà nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá), YCE ló rọ igbákejì Ààrẹ wí pé kó má kọ̀wé fi ipò rẹ̀ sílẹ̀.
Bákan náà ni ẹgbẹ́ YCE rọ Ààrẹ Muhammadu Buhari pé kó má ṣe gbọ́ ohun táwọn kan ń sọ fún un lórí ọ̀rọ̀ Osinbajo wí pé kò rántí bí Osinbajo ṣe dúró tìì láti ìgbà tí wọ́n ti jọ bẹ̀rẹ̀.
Lọ́jọ́ Ẹ̀tì ni iléeṣẹ́ Ààrẹ fìdíi rẹ̀ múlẹ̀ pé Ààrẹ Muhammadu Buhari ló pàṣẹ ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ fáwọn olùrànlọ́wọ́ márùndínlógójì ìgbákejì Ààrẹ Osinbajo. Àmọ́ iléeṣẹ́ Ààrẹ ṣàlàyé pé dídá tí wọ́n dá àwọn olùrànlọ́wọ́ Osinbajo dúró ní-ín ṣe pẹ̀lú ìgbìyànjú Ìjọba àpapọ̀ láti dín owó tí Ìjọba ń ná fún ìṣèjọba kù. àtẹ̀jáde náà ní ọrọ ìdádúró yìí náà ti kọ́kọ́ kan díẹ̀ nínú àwọn olùrànlọ́wọ́ Ààrẹ.
Garba Shehu ní àwọn ipò olóṣèlú kan láwọn ti yọ kúrò tí wọ́n kò sì tún àwọn èèyàn mìíràn yàn sí ipò míì bí Buhari ṣe wọlé lẹ́ẹ̀kejì. Ó ní kò sí ìjà láàrin Buhari àti Osinabjo lásìkò yìí.
Ṣaájú ni ọ̀gbẹ́ni Laolu akande to jẹ oluranlọwọ fun ìgbákejì Ààrẹ Oṣinbajo ti kọ́kọ́ fi síta pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni pé Ààrẹ Buhari dá àwọn oluranlọwọ Oṣinbajo márùndínlógójì dúró lẹ́nu iṣẹ́ wọn
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/ijo-katoliki-bere-iwaadi/
Ìjọ Kátólíkì Bẹ̀rẹ̀ Ìwáàdì Lẹ̀yìn Tí Àwọn Sisitá Méjì Lóyún Ójijì
Ìjọ Kátólíkì bẹ̀rẹ̀ ìwáàdì lẹ̀yìn tí àwọn sisitá méjì lóyún ójijì
Ìjọ Kátólíkì bẹ̀rẹ̀ ìwáàdì lẹ̀yìn tí àwọn sisitá méjì lóyún ójijì
Fẹ́mi Akínṣọlá
Eemọ̀ lukutu pẹ́bẹ́,kò síbi tí ìṣe ò sí. Ayé dojú kejì, wọ́n ń bámí ẹran níhòòdí ọmọ èèyàn. Ìjọ Kátólíìkì ti ń ṣe ìwádìí bí àwọn sista méjì kan ṣe lóyún lẹ́yìn tí wọ́n lọ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nílẹ̀ Áfírìkà. Àwọn obìnrin méjéèjì náà tó jẹ́ olùgbé ìlú Sicily, lórílẹ̀-èdè Italy, tí wọ́n kìí ṣe ọmọ ìjọ kan náà, ni wọ́n ń dúró de ọjọ́ ìkúnlẹ̀ báyìí.
Ọ̀kan lára àwọn obìnrin ọ̀hún, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lọ sí ilé ìwòsàn nítorí inú rírun, kí Dókítà tó fún- un ní ìròyìn pé oyún ti dúró sára rẹ̀. Ìjọ Kátólíìkì tó wà ní ìlú Rome sọ fún àwọn akọ̀rọ̀yìn pé, ìgbà tí àwọn obìnrin náà rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ adúláwọ̀ ni wọ́n ní ìbálòpọ̀. Ìjọ ọ̀hún tẹ̀síwájú pé àwọn obìnrin náà rú òfin tó jẹ mọ́ Ẹ̀sìn àti iṣẹ́ tí wọ́n gbà, bẹ́ẹ̀ ni ìwádì ti bẹ̀rẹ̀ lori bí wọ́n ṣe di aláboyún òjijì.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ni olórí ìjọ Kátólíìkì lágbàáláayé , Pope Francis ti sọ ṣaájú pé, àwọn Bísọ́ọ̀bù kan má ń fi ipá bá àwọn sista ní àjọṣepọ̀, kódà ó ní wọ́n ń fi àwọn mìíràn lára wọn ṣe ẹrú ìbálòpọ̀. Popu ṣ��làyé pé, bí àwọn Bísọ́ọ̀bù yìí ṣe ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin náà jẹ́ ìsòro ńlá nínú Ìjọ Kátólíìkì.
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/lai-mohammed-fa-omo-naijiria/
Lai Mohammed fa o̩mo̩ Naijiria létí lórí ìròyìn òfegè
Lai Mohammed fa ọmọ Nàìjíríà létí lórí ìròyìn òfegè
Fẹ́mi Akínṣọlá
Mínísítà ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti Ìròyìn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Lai Mohammed ti ní ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ ṣí í ṣe àmójútó àtagbà ojú òpó ayélujára báyìí. Ìgbésẹ̀ yìí ni láti ṣe àfọ̀mọ́ ojú òpó ayélujára kí àdínkù leè bá ayédèrú Ìròyìn àtàwọn ọrọ kòbákùngbé tó ń jẹyọ.
Lai Mohammed sọ ọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé oníròyìn kan tó wáyé nílùú Abuja Mínísítà ní èyí kò yọ àwọn oníṣẹ́ ìròyìn sílẹ̀ o. Ó ní ilé iṣẹ́ Ìròyìn tó bá ta féle fèle gan yóó fara kó o. Àtúnṣe tí wọ́n fẹ́ bẹ̀rẹ̀ yìí yóò tàn dé ojú òpó ayélujára èyí tó sàpèjúwe pé “ó ti kọjá àtúnṣe”.
Lai Mohammed tún ní “láti ìgbà tí a ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò àyípadà yìí ni àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ti kàn sí wa pé kí a bojú wo bí a ṣe le ṣe ìlanilọyẹ̀ lórí àwọn ayélujára náà a kò sì ní pa eléyìí tì”. Mohammed ni kò sí ìjọba gidi kan tí yóò jókòó káwọ́ gbera kí ìròyìn òfegè sì máa fò kiri t’òun tọ̀rọ̀ àlùfàǹṣá eléyìí tó leè dáná sun orílẹ̀-èdè láì sí àyẹ̀wò kankan.
“Idi niyii ti ao fi maa koju ayederu iroyin ati ọrọ alufansa ayafi bi a ba to le gbogbo rẹ danu”. O ni tori awọn ti ṣe agbekalẹ igbimọ kan ti aarẹ Buhari fọwọ si lati kọju awọn ọrọ alufansa.
Main
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/local-news/atiku-tun-padanu-nile/
Atiku tún pàdánu nílé e̩jó̩ tó ga jù
Atijo tun padanu nile ejo to ga ju Lati owo Yinka Alabi Ile-ejo to ga ju lo ni orileede yii ti se idajo lori ejo ti oludije dupo Aare ni abe egbe oselu PDP, Alhaji Atiku Abubakar. Ile-ejo ni Aare Muhammadu Buhari naa ni o jawe olubori nibi ibo Aare to waye naa. Olori egbe oselu APC, Adams Oshiomole ni “oro omugo lo maa n yato,bakan naa ni ti ologbon ri”. O ni ile-ejo lo je ki o ye awon egbe oselu alatako mo pe ipo Aare kii se ohun ti awon omo Yahoo kan le ko jo loru. O ni orileede yii ti koja ibo “aburakadaka”. Aare Mohammadu Buhari naa ni inu oun dun si idajo naa, oun si maa feran ki egbe oselu PDP darapo mo oun ki awon le jo gbe Naijiria de ebute ogo. Atiku Abubakar ni inu oun ko baje pe egbe oun padanu ejo naa nile ejo giga. O ni ija ti o dara ni oun ja,ni eyi to mu ki idagbasoke ba eto oselu orileede yii.
Atiku tún pàdánu nílé e̩jó̩ tó ga jù
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/akpabio-fajuro-si-owo/
Akpabio fajúro sí owó ìnákúùná Niger Delta
Akpabio fajuro si owo inakuna Niger Delta Lati owo Yinka Alabi Ijoba apapo ti Senato Akpabio n soju fun lo ti gbanaje lori awon ise ajanbaku to n waye ni agbegbe Niger Delta.
Akpabio ni o ye ki ise ijoba maa te siwaju bi ijoba se n yi pada ni amo o ni ko ri bee ni oro orileede yii. O ni bi eto ijoba se n yi pada ni awon eniyan bere si ni seto owo miran fun ise miran. Won wa n pa ise ti awon Kan ti se ti. Akpabio ni eyi ni lati dawo duro nitori pe owo rogun rogun ni ijoba apapo n ya soto fun agbegbe naa ni odoodun.
Akpabio ni owo ina apa yii ti bere lati bii odun metalelogun seyin bayii. O ni awon ara agbegbe naa si n pariwo pe ijoba n ri owo ni agbegbe awon bee ni ijoba naa ko sise si agbegbe naa.
Eyi wa lara ohun to da omi tutu si okan Senato Akpabio. Lara itesiwaju agbegbe naa lo mu ki ipade pajawiri waye ni Abuja laarin awon gomina agbegbe naa pelu Aare Mohammadu Buhari lonii.
Main
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/mama-aadorin-odun-roo/
Màmá àádó̩rin o̩dún ròó pin sí ófíìsì àwo̩n oníná mò̩nàmó̩ná
Màmá àádó̩rin o̩dún ròó pin sí ófíìsì àwo̩n oníná mò̩nàmó̩ná Lati owo Yinka Alabi Iya agbalagba ti ko din ni aadorin odun lo lo roo pin si ofiisi ajo apina-ka (IBEDC) Ibadan Electricity Distribution Company to fi ikale si ilu Osogbo. Mama yii di awon nnkan to le nilo ti ebi ba n paa bii – sitoofu idana, abo idana, kerosinni, abo ijehun ati awon nnkan ilo inu ile miran.
Kin ni “mama yii ri lobe ti o fi waro owo”? Mama ni oun ti san owo fun mita ti ko ni itanje, to je pe bi eniyan ba se n loo ni owo re se n lo. Mama ni oun reti remu, oun ko gburo awon ajo onina yii lo ba mu ki oun kuku see ni “oju awo ni awo fi n bu obe”.
Ni igba ti awon ara ofiisi yii tii pe mama yii ko mu ni oro awada, Kia ni won ranse si olu ile ise won to wa ni ilu Ibadan. Ibe naa ni ase ti gun un ki won mu mama naa lo ile ki won si lo so mita ina naa.
Awon ajo IBEDC ilu Osogbo pa akiti mole won si gbe mama de ile re ni Atelewo ni ilu Osogbo. Won so mita naa mo ile , won si pari gbogbo eto miran to tun ye ki won to kuro ni ile mama naa.
http://iroyinowuro.com.ng/2019/10/29/mama-aado%cc%a9rin-o%cc%a9dun-roo-pin-si-ofiisi-awo%cc%a9n-onina-mo%cc%a9namo%cc%a9na/
0 notes
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/e-e-%e1%b9%a3i-nonba-mu-loyo/
Ẹ ẹ̀ ṣi nọ́ńbà mú l’Ọyọ, gbogbo owó yín tí mo bá ná, ẹ ó rí n tí mo fi se – Seyi Makinde
Ẹ ẹ̀ ṣi nọ́ńbà mú l’Ọyọ, gbogbo owó yín tí mo bá ná, ẹ ó rí n tí mo fi se…..Seyi Makinde
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà ní bí Ọlọ́run bá sẹ̀rí ì rẹ,jẹ́ kí èèyàn náà ó sẹ̀rí ì rẹ . Gomina ìpínlẹ̀ Ọyọ, Onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde tún ti fọwọ́ méjéèjì sọ̀yà fún àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọyọ pé, òun kò ní ná owó wọn ní inakuna. Ó ní gbogbo ohun tí òhun bá fi owó wọn se, ni wọn yóò fi ojú rí. Gomina Makinde jẹjẹ yii lọjọ Aje lasiko to n se ayẹwo awọn isẹ agbase mẹta nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Ọyọ.
Gomina Makinde lo sabẹwo gareji ọkọ to wa ni Sango, ile iwosan Jericho ati ile igbẹbi tuntun to wa ladugbo Jericho bakan naa, to si koro oju si ipo tawọn dukia ijọba ọhun wa, paapa awọn ilẹ ati ọpọ ohun eelo ti wọn ti pa ti. Gomina ni asa ti ko dara ni ki wọn maa na owo ilu ninakuna lori awọn isẹ agbase kan, ki wọn si pada wa pa isẹ ọhun ti nigba ti isẹ naa ba de idaji, lai naani owo tuulu ti wọn ti na le lori.
Makinde ni iru asa yii lo wọpọ lasiko ijọba to kogba wọle nipinlẹ Ọyọ, to si tun seleri fawọn eeyan ipinlẹ naa pe ijọba oun yoo ri daju pe wọn fi oju ara wọn ri ohun ti oun ba fi owo ilu se.
Makinde wá pàsẹ fún olùdarí ilée tó ń sàkóso ètò ìrìnà lójú pópó ní ìpínlẹ̀ Ọyọ, Ọmọwe Akin Fagbemi, láti gbé olú iléeṣẹ́ rẹ̀ lọ sí gárèjì ọkọ̀ àtijọ́ to wà ní Sango, pẹ̀lú ìlérí pé òun yóò pèsè àwọn ohun èlò to yẹ síbẹ̀ fún ìdẹ̀rùn iṣẹ́ wọn.
Iroyinowuro
0 notes