Tumgik
#ẹgba
edeyorubarewa · 5 years
Photo
Tumblr media
ÌṢẸ̀LẸ̀ TÓ ṢẸLẸ̀ LÁÀÁRÍN ẸNI Ọ̀WỌ̀ RANSOME-KUTI ÀTI ỌBA LỌ́LA. Ní ọdún 1945, wọ́n mú ọmọdékùnrin ìpáǹle kan wá sí iwájú Ẹni-ọ̀wọ̀ Isreal Olúdọ̀tun Ransome-Kuti (ọ̀gá àgbà fún ilé ìwé Gírámà Abẹ́òkúta nígbà náà) fún ẹ̀ṣẹ̀ tó tọ́ sí ẹgba pankẹ́rẹ́. Ilé ìwé kan ní Ilé Ifẹ̀ ni ọmọ yìí ń lọ tẹ́lẹ̀rí kí wọ́n tó múu wá sí Abẹ́òkúta láti le kọ́ ẹ̀kọ́ tó yè kooro, kí ó sì leè ta yọ. Bí Alàgbà Kútì ti gbé ẹgba sókè láti nàá, ni ọmọdékùnrin yìí pariwo tòò 'ẹ ó na ọmọ ọba bí?'. Àyàa Kútì là gààrà, bótilẹ̀ jẹ́ wípé inú ń bíi. Kò sẹ́ni tó jẹ́ gbé iná wojú ẹkùn rẹ̀ láti ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún tó ti jẹ́ ọ̀gá àgbà, á ń bèlètàsé ìgbà tó ń ṣe olùkọ́ ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́. 'Àyà mà kò ọ́ o, ẹgbẹ́ n bí go? Taló gún'yán fún ọ tó ní t'ọbẹ̀ ò ṣòro? Ẹ gbé e pọ̀n' Kútì bú ramúramù. Ọ̀kan nínú àwọn ìgìrìpá oníwèé kẹwàá bá gbé ọmọdékùnrin yìí pọ̀n, pẹ̀lúu bẹ́ẹ̀ náà ọmọ yìí ṣì ń janpata, 'a kìí ṣí'wọ́ lu'mí, ẹnìkan kìí lu ọba lọ́la' ni ọmọ yìí ń pariwo. Ẹ̀yín etí Kútì ni gbogbo ọ̀rọ̀ yí ń bọ́ sí, kò kúkú bẹ̀rù ẹnìkan àfi ọba Èdùmàrè, kódà Kútì kò bẹ̀rù ọba tàbí ìjòyè kíjòyè. 'fàì fàì fàì fàì' pankẹ́rẹ́ ń dún kíkan kíkan lára jagunlabí. 'Fẹ́mú! Kọ́kọ́rọ́, gbọin', ni ọba lọ́la tó ti ń ké bá dákẹ́ fẹ́mú bí ẹní ṣẹ̀ṣẹ̀ gba oúnjẹ alẹ́ Olúwa, tani ń jẹun t'ájá ń jù'rù?. Kútì kìí nílọ̀ wípé ní ọjọ́ tó bá tún dá aṣọ irú ẹ̀ ṣ'orò; àjẹkún ìyà ni yóò jẹ. Ìpátá ọmọkùnrin ọjọ́ kìíní àná ló padà wá di Ọba pàtàkì. Òun ni Ọọ̀ni Àádọ́ta ti ilé Ifẹ̀ (1980-2015); Ọba Okunade Sijuwade Olubuse III (1930-2015). Yorùbá Kan ń ṣ'àdúrà wípé kí Elédùà ó mú eèpẹ̀ buúkú kúrò lójú àwọn Bàbá wọ̀nyí. #EdeYorubaRewa (at Birmingham city centre) https://www.instagram.com/p/B28ldJhp3jV/?igshid=f0kbt7rg2pd8
1 note · View note
naijavoicemedia · 3 years
Text
Olu Kọbapẹ naa ti waja o – Alaroye
Olu Kọbapẹ naa ti waja o – Alaroye
Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta Olu ilu Kọbapẹ, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun, Ọba Olufẹmi Taylor, ti waja. Ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila, ọdun 2021 yii, ni Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba to jẹ Oluwo Ọba, fi atẹjade kan sita, nibẹ lo ti sọ ọ di mimọ pe pẹlu aṣẹ Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, oun kede ipapoda Olu Kọbapẹ, Ọba Olufẹmi Taylor. Oloye Ọṣọba tẹsiwaju ninu…
View On WordPress
0 notes
adewumiidowupaul · 3 years
Text
SODEKE: THE BEAU IDÉAL OF THE ẸGBA PEOPLE
SODEKE: THE BEAU IDÉAL OF THE ẸGBA PEOPLE
Sodeke was born in Iporo in the Ẹgba forest, his father, Rogidi was a farmer, his mother, Efuwo, was said to be the daughter of Lelu-Origi, a traditional high chief. When his father died, he became the head of the Rogidi family, like his father too, he was a farmer and by the end of 1780’s, he had become one of the most successful farmers in the Ẹgba forest. Shortly after the Owu War of…
Tumblr media
View On WordPress
0 notes
ojb4africa · 6 years
Photo
Tumblr media
To God elédùmarè Allah 🙏🙏 #iyil2019 #indigenousLanguage #culture #africa #nigeria #lagosnigeria #facetv #ibilẹ #akomolowe #opomulerotv #lagos #beriolaentertainment #woliarole #aremuafolayan #lagos #ojogbonoladele #yorubaplus #makeuslaugh #yorubademons #beriolaentertainment #yorubanimirán #lagosnigeria #professor #facetv#fela #OjulowoomoYoruba #ojogbon #happweekend #alake #ẹgba #ogun #ekiti #ondo #ijebu #egba #macgregor #ololuabi #oluronbi @oluwayemi01 @praise_adeolu @officialarole @adedimejilateef @beriola_khalidayanshina @aremumimostwantedlikecrudeoil @officialyemielesho @iamlizzy @thecuteabiolafanspage @samuelajirebi @alutaemir @officialarole (at Ogun (state)) https://www.instagram.com/p/BvW2AzznHZu/?utm_source=ig_tumblr_share&igshid=j7b422htfkiz
0 notes
newsnigeria · 5 years
Text
Check out New Post published on Ọmọ Oòduà
New Post has been published on http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/omooba-mewaa-lo-du-oye-pelu-mi-alaafin-o%cc%a9yo%cc%a9/
Ọmọọba mẹwàá ló du òyè pẹ̀lú mi – Aláàfin Ò̩yó̩
Ọmọọba mẹwàá ló du òyè pẹ̀lú Adeyẹmi, tó sì já mọ lọ́wọ́.
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta, ti pé ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rín lókè eèpẹ̀ bẹ́ẹ́ ló ti lo ọdún méjìdínláàdọ́ta lórí ìtẹ́ àwọn baba ńlá rẹ̀.
Òjò ti ń pa igún bọ̀, ọjọ́ ti pẹ́ ni ọ̀rọ̀ Ọba Adeyẹmi, tori pé ojú rẹ̀ ti rí ọ̀pọ̀ ìrírí sẹ́yìn kó tó jọba àti lẹ́yìn tó jẹ ọba tán.
kìí kúkú se ààfin ọba ni wọ́n ti wo ọba Adeyẹmi nígbà tó wà léwe, nítorí pé a rí i kà pé ó ti gbé nílùú Abẹokuta, Isẹyin àti Eko gan an rí. Ọmọ-Ọba ni Lamidi Ọlayiwọla, nítorí inú ìdílé Ọba Alówólódù nílùú Ọyọ ni wọ́n ti bíi, bàbá àti baba-baba rẹ̀ sì jẹ Alaafin pẹ̀lú .
Orúkọ bàbá rẹ̀ ni Ọba Adeniran Adeyẹmi keji, ẹni to wa lori itẹ, ki ijọba to rọ ọ loye nitori pe o n lọwọ ninu oselu sise Ọjọ Kẹẹdogun, osu Kẹwa ọdun 1938 ni wọn bi Lamidi Ọlayiwọla, eyi tii se ọdun mọkanlelọgọrin sẹyin
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọba ni, síbẹ̀, wọ́n kò wo Lamidi kékeré nínú ààfin Ọyọ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ọlá, ìlú Isẹyin lẹba Ọyọ ni wọ́n ti wo dàgbà, tó sí tún lọ sílé kéú níbẹ̀ Lamidi Ọlayiwọla tún gbé ní ọ̀dọ̀ ọ Alake tilẹ̀ Ẹgba, Ọba Ọladepo Ademọla, kó tó di pé wọ́n tún rọ Alake yìí lóyè Ó tún lọ gbé Ọlọla-binrin Kofoworọla Abayọmi ladugbo Keffi, ní Ikoyi nílùú Eko, tó si lọ sílé ẹkọ Mọda, Ọbalende Modern School Lẹ́yìn èyí ló mórílé ileẹkọ girama St.Gregory‘s College, Ọbalende. Ìmọ̀ nípa iṣẹ́ Amòfin ló wu Lamidi láti kọ́ nílé ẹkọ fásitì kan nílùú oyinbo, ó ku ọjọ́ méjì tí yóò tẹ ọkọ̀ létí ni wọ́n rọ bàbá rẹ̀ lóyè, tí kò sì leè lọ mọ́.
Iṣẹ́ àáyàn láàyò tí Lamidi kọ́kọ́ mú se nígbà èwe rẹ̀ ni iṣẹ́ adójútòfò (Insurance), tó sì tún jẹ́ akọsẹ-mọsẹ abẹ̀sẹ́kùbíòjò, bẹ́ẹ̀ sì ló tún máa ń se eré i ìdárayá títí di kóko yii lai naani ọjọ ori rẹ Ki Ọlayiwọla to gun ori itẹ àwọn baba ńlá rẹ̀, iyawo meji lo ni, Olori Abibat Adeyẹmi, tí wọ́n ń pè ní iya Dodo àti Olori Rahmat Adedayọ Adeyẹmi, tí wọ́n mọ̀ sí iya Ilé kótó.
Orúkọ àkọ́bí ọmọ Ọba Adeyẹmi ni Kudirat Akọfade Erediuwa, ẹni tó ti jáde láyé báyìí. A ríi gbọ́ pé èèyàn mẹ́wàá ló du ìtẹ́ Aláàfin pẹ̀lú Lamidi Ọlayiwọla lẹ́yìn ikú u Aláàfin Bello Gbadegẹsin Ladigbolu kejì.
Lára àwọn tó du ipò náà ni Àrẹ̀mọ Sanni Gbadegẹsin, Ọmọọba Ọlanitẹ Ajagba, Ọmọọba Afọnja Ilaka, Ọmọọba Sanda Ladepo Ọranlọla àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ọjọ́ Kẹrinla osu Kinni ọdun 1971 ni Ọba Lamidi Ọlayiwọla gun orí ìtẹ́ àwọn baba ńlá rẹ̀, tó sì di Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta Aláafin máa ń sọlá láàrín àwọn aya rẹ̀, paàpá àwọn tó jẹ́ ọ̀dọ́, tí wọ́n sì tún jẹ ojú ní gbèsè ni ọ̀dẹ̀dẹ̀, ó sì máa ń mu wọn yangàn lọ sí ọ̀pọ̀ ibi tó bá ń lọ Lára àwọn arẹwà aya Aláàfin ni Olorì Ola, Memunat, Badrat. Ní ẹni ọdún mọkanlelọgọrin, Ọba Adeyẹmi ní okun àti agbára tó ju tàwọn èwe mìíràn lọ, tó sì bí ìbejì ní ẹ̀ẹ̀mejì àti ìbẹta.
Onkọtan, Onpitan ati ọlọpọlọ pipe ni Alaafin, ti ko si gbagbe ọpọ itan ilẹ Yoruba ati Nàìjíríà láì náání ọjọ́ orí rẹ̀. Lára àwọn awọn ọmọ Aláàfin tó gbajúgbajà ni Amofin Babatunde, Ọmọọba Fọlasade, Taibat, Nurudeen Adesẹgun, Akeem Adeniyi (Skimmeh), Adebayọ Fatai ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ọmọ Aláàfin kan ti di ipò òsèlú mú sẹ́yìn, tí àwọn mìíràn sì tún wà nípò òsèlú. Lára wọn la ti rí Fọlasade àti Taibat tí wọ́n ti jẹ Kọmíṣọ́nnà nipinlẹ Ọyọ nígbà kan rí àti Akeem Adeniyi, tó ti jẹ alága ìjọba ìbílẹ̀ ri, tó tún lọ sílé aṣòfin àpapọ̀ ilẹ wa Ọba Adeyẹmi gbáfẹ, o gbóge, tó sì rẹwà lọ́kùnrin.
Main
0 notes